Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 3:11 - Yoruba Bible

11 Wò ó! Wọn yóo gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé kọjá níwájú yín sinu odò Jọdani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Kiyesi i, apoti majẹmu OLUWA gbogbo aiye ngòke lọ ṣaju nyin lọ si Jordani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Àpótí májẹ̀mú Olúwa gbogbo ayé ń gòkè lọ sí Jordani ṣáájú u yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 3:11
15 Iomraidhean Croise  

OLUWA, o tóbi pupọ, tìrẹ ni agbára, ògo, ìṣẹ́gun, ati ọlá ńlá; nítorí tìrẹ ni ohun gbogbo ní ọ̀run ati ní ayé. Tìrẹ ni ìjọba, a gbé ọ ga bí orí fún ohun gbogbo.


Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un? Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé.


OLUWA ló ni ilẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, òun ló ni ayé, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀;


Àwọn òkè ńlá yọ́ bí ìda níwájú OLUWA, àní, níwájú OLUWA gbogbo ayé.


Ẹ wá wo àwọn eniyan mi! Ọmọde ni àwọn olórí àwọn eniyan mi; àwọn obinrin ní ń pàṣẹ lé wọn lórí. Ẹ̀yin eniyan mi, àwọn olórí yín ń ṣì yín lọ́nà, wọ́n sì ti da ọ̀nà yín rú.


Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ, Ọlọrun gbogbo ayé ni à ń pè é.


Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè? Nítorí ẹ̀tọ́ rẹ ni; kò sì sí ẹni tí ó gbọ́n tó ọ láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè, ati ni gbogbo ìjọba wọn.


Ẹ dìde kí ẹ tẹ àwọn ọ̀tá yín mọ́lẹ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Nítorí n óo mú kí ìwo rẹ lágbára bí irin, pátákò ẹsẹ̀ rẹ yóo sì dàbí idẹ; o óo fọ́ ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè túútúú, o óo sì ya ọrọ̀ wọn sọ́tọ̀ fún OLUWA, nǹkan ìní wọn yóo jẹ́ ti OLUWA àgbáyé.


OLUWA óo dẹ́rùbà wọ́n, yóo sọ gbogbo oriṣa ilé ayé di òfo, olukuluku eniyan yóo sì máa sin OLUWA ní ààyè rẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè.


OLUWA yóo wá jọba ní gbogbo ayé; Ọlọrun nìkan ni gbogbo aráyé yóo máa sìn nígbà náà, orúkọ kanṣoṣo ni wọn yóo sì mọ̀ ọ́n.


Ó bá dáhùn, ó ní, “Àwọn wọnyi ni àwọn meji tí a ti fi òróró yàn láti jẹ́ òjíṣẹ́ OLUWA gbogbo ayé.”


Angẹli náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ń lọ sí igun mẹrẹẹrin ayé lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn han Ọlọrun ẹlẹ́dàá gbogbo ayé.”


Nítorí náà, kí ẹ mọ̀ lónìí pé, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń lọ níwájú yín, bíi iná ajónirun. Yóo pa wọ́n run, yóo sì tẹ orí wọn ba fun yín, nítorí náà, kíá ni ẹ óo lé wọn jáde, tí ẹ óo sì pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.


Nígbà tí ẹsẹ̀ àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé bá kan odò Jọdani, odò náà yóo dúró; kò ní ṣàn mọ́, gbogbo omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè yóo sì wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan