Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 24:2 - Yoruba Bible

2 Ó wí fún gbogbo wọn pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Nígbà laelae, òkè odò Yufurate ni àwọn baba yín ń gbé: Tẹra, baba Abrahamu ati Nahori. Oriṣa ni wọ́n ń bọ nígbà náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Bayi ni OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Awọn baba nyin ti gbé ìha keji Odò nì li atijọ rí, ani Tera, baba Abrahamu, ati baba Nahori: nwọn si sìn oriṣa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Joṣua sì sọ fun gbogbo ènìyàn pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli, wí: ‘Nígbà kan rí àwọn baba ńlá yín Tẹra baba Abrahamu àti Nahori ń gbé ní ìkọjá odò Eufurate, wọ́n sì sin àwọn òrìṣà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 24:2
16 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Serugi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori.


Nígbà tí Nahori di ẹni ọdún mọkandinlọgbọn ni ó bí Tẹra.


Nígbà tí Tẹra di ẹni aadọrin ọdún ni ó bí Abramu, Nahori, ati Harani.


Àkọsílẹ̀ ìran Tẹra nìyí: Tẹra ni baba Abramu, Nahori ati Harani. Harani sì ni baba Lọti.


Ní àkókò yìí, Labani wà níbi tí ó ti ń gé irun àwọn aguntan rẹ̀, Rakẹli bá jí àwọn ère oriṣa ilé baba rẹ̀ kó.


Mo mọ̀ pé ọkàn rẹ fà sí ilé ni o fi sá, ṣugbọn, èéṣe tí o fi jí àwọn ère oriṣa mi kó?”


Ní ti àwọn ère oriṣa rẹ, bí o bá bá a lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, pípa ni a óo pa olúwarẹ̀. Níwájú gbogbo ìbátan wa, tọ́ka sí ohunkohun tí ó bá jẹ́ tìrẹ ninu gbogbo ohun tí ó wà lọ́dọ̀ mi, kí o sì mú un.” Jakọbu kò mọ̀ rárá pé Rakẹli ni ó jí àwọn ère oriṣa Labani kó.


Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Nahori, àní, Ọlọrun baba wọn ni onídàájọ́ láàrin wa.” Jakọbu náà bá búra ní orúkọ Ọlọrun tí Isaaki baba rẹ̀ ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù.


Gbogbo wọn bá dá àwọn ère oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn jọ fún Jakọbu, ati gbogbo yẹtí tí ó wà ní etí wọn, Jakọbu bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ lábẹ́ igi oaku tí ó wà ní Ṣekemu.


Abramu, tí a tún ń pè ní Abrahamu.


Ẹ wo Abrahamu baba yín, ati Sara tí ó bi yín. Òun nìkan ni nígbà tí mo pè é, tí mo súre fún un, tí mo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ eniyan.


kí o sì sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Jerusalẹmu pé: “Ilẹ̀ Kenaani ni a bí ọ sí; ibẹ̀ ni orísun rẹ. Ará Amori ni baba rẹ ará Hiti sì ni ìyá rẹ.


ọmọ Jakọbu, ọmọ Isaaki, ọmọ Abrahamu, ọmọ Tẹra, ọmọ Nahori,


Lẹ́yìn náà, o óo wí báyìí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Ará Aramea, alárìnká, ni baba ńlá mi, ó lọ sí ilẹ̀ Ijipti, ó sì jẹ́ àlejò níbẹ̀. Wọn kò pọ̀ rárá tẹ́lẹ̀, ṣugbọn níbẹ̀ ni wọ́n ti di pupọ, wọ́n sì di orílẹ̀-èdè ńlá, tí ó lágbára, tí ó sì lókìkí.


Bí kò bá wá wù yín láti máa sin OLUWA, ẹ yan ẹni tí ó bá wù yín láti máa sìn lónìí. Kì báà ṣe àwọn oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò, tabi oriṣa àwọn ará Amori tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ wọn. Ṣugbọn ní tèmi ati ilé mi, OLUWA ni àwa óo máa sìn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan