Joṣua 23:2 - Yoruba Bible2 ó bá pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, àwọn àgbààgbà, ati àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, ati àwọn alákòóso, ó wí fún wọn pé, “Mo ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí mi; Faic an caibideilBibeli Mimọ2 Joṣua si pè gbogbo Israeli, ati awọn àgba wọn, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn, o si wi fun wọn pe, Emi di arugbó tán, emi si pọ̀ li ọjọ́: Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní2 Ó sì pe gbogbo Israẹli jọ: àgbàgbà wọn, olórí wọn, adájọ́ àti àwọn ìjòyè, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti pọ̀ ní ọdún èmi ti di arúgbó. Faic an caibideil |
Dafidi ọba pe gbogbo àwọn olórí ní ilẹ̀ Israẹli jọ sí Jerusalẹmu, àwọn olórí láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn olórí àwọn ìpín tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún ọba, àwọn ọ̀gágun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun, ati ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ alabojuto ohun ìní ati ẹran ọ̀sìn ọba, àwọn tí wọ́n ń tọ́jú àwọn ọmọ ọba, àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ààfin, àwọn eniyan pataki pataki ati àwọn akọni ọmọ ogun, gbogbo wọn péjọ sí Jerusalẹmu.