Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 23:1 - Yoruba Bible

1 Ó pẹ́ lẹ́yìn tí OLUWA ti fún Israẹli ní ìsinmi, tí kò sí ogun mọ́ láàrin àwọn ati gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó yí wọn ká, Joṣua ti di àgbàlagbà ní àkókò yìí, ogbó sì ti dé sí i;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O si ṣe li ọjọ́ pipọ̀ lẹhin ti OLUWA ti fi isimi fun Israeli lọwọ gbogbo awọn ọtá wọn yiká, ti Joṣua di arugbó, ti o si pọ̀ li ọjọ́;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, nígbà tí Olúwa sì ti fún Israẹli ní ìsinmi kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká, nígbà náà Joṣua sì ti di arúgbó.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 23:1
15 Iomraidhean Croise  

ó di arúgbó kùjọ́kùjọ́, kí ó tó kú.


Ní àkókò yìí, Dafidi ọba ti di arúgbó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣọ tí ó nípọn ni wọ́n fi ń bò ó, òtútù a tún máa mú un.


Dafidi ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi, yóo sì máa gbé Jerusalẹmu títí lae.


Àwọn wọnyi ni àwọn olórí ìdílé ati olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati olórí ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, ati àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ aṣojú ọba ní gbogbo ìpínlẹ̀ ní oṣooṣù, títí ọdún yóo fi yípo ni wọn máa ń yan ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000) eniyan, tí wọn ń pààrọ̀ ara wọn.


Nígbà tí Abija ọba kú, wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní àkókò rẹ̀, alaafia wà ní ilẹ̀ náà fún ọdún mẹ́wàá.


Ó kó gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ ati àwọn pẹpẹ tí wọ́n ti ń sun turari ní gbogbo àwọn ìlú Juda jáde. Alaafia sì wà ní àkókò ìjọba rẹ̀.


Nítorí náà Jehoṣafati jọba ní alaafia, nítorí pé Ọlọrun fún un ní ìsinmi ní gbogbo àyíká rẹ̀.


Ó dáwọ́ ogun dúró ní gbogbo ayé, ó ṣẹ́ ọrun, ó rún ọ̀kọ̀, ó dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun.


Wọ́n rìn wọnú àfonífojì bíi mààlúù, Ẹ̀mí OLUWA sì fún wọn ní ìsinmi. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe darí àwọn eniyan rẹ̀, kí ó lè gba ògo fún orúkọ rẹ̀.


Ó ní, “Òní ni mo di ẹni ọgọfa ọdún (120), kò ní ṣeéṣe fún mi mọ́, láti máa fò síhìn-ín sọ́hùn-ún. OLUWA ti wí fún mi pé, n kò ní gun òkè odò Jọdani yìí.


Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Mose, ó sì pín in fún àwọn ọmọ Israẹli; ní ẹlẹ́yà-mẹ̀yà. Lẹ́yìn náà, wọ́n sinmi ogun jíjà.


Ní àkókò yìí, Joṣua ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí i. OLUWA bá sọ fún un pé, “Ogbó ti dé sí ọ, ṣugbọn ilẹ̀ pupọ ni ó kù láti gbà.


OLUWA fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo àyíká wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Kò sì sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè ṣẹgun wọn, nítorí pé OLUWA ti fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́.


Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun yín ti fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn; nítorí náà, ẹ pada lọ sí ilẹ̀ yín, níbi tí ohun ìní yín wà, àní ilẹ̀ tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín ní òdìkejì odò Jọdani.


Nisinsinyii, ọba ni yóo máa ṣe olórí yín. Ní tèmi, mo ti dàgbà, ogbó sì ti dé sí mi. Àwọn ọmọ mi sì ń bẹ lọ́dọ̀ yín. Láti ìgbà èwe mi ni mo ti jẹ́ olórí fun yín títí di àkókò yìí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan