Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 21:3 - Yoruba Bible

3 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA, àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú ati pápá tí ó yí wọn ká, ninu ilẹ̀ ìní wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Awọn ọmọ Israeli si fi ilu wọnyi pẹlu àgbegbe wọn fun awọn ọmọ Lefi ninu ilẹ-iní wọn, nipa aṣẹ OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Àwọn ọmọ Israẹli sì fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú wọ̀nyí, àti ilẹ̀ pápá oko tútù lára ilẹ̀ ìní tiwọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 21:3
7 Iomraidhean Croise  

Ìfibú ni ibinu wọn, nítorí pé ó le, ati ìrúnú wọn, nítorí ìkà ni wọ́n. N óo pín wọn káàkiri ilẹ̀ Jakọbu, n óo sì fọ́n wọn ká ààrin àwọn eniyan Israẹli.


Gbogbo ìlú tí ẹ óo fún wọn yóo jẹ́ mejidinlaadọta pẹlu ilẹ̀ pápá tí ó yí wọn ká.


ní Ṣilo ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sọ fún wọn pé, “OLUWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mose pé kí wọ́n fún wa ní ìlú tí a óo máa gbé ati pápá oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa.”


Ilẹ̀ kinni tí wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọmọ Kohati. Nítorí náà, gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ ìran Aaroni alufaa gba ìlú mẹtala lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Juda, ẹ̀yà Simeoni, ati ẹ̀yà Bẹnjamini.


Gbogbo ìlú tí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ninu ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ mejidinlaadọta pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan