Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 20:4 - Yoruba Bible

4 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan sá lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọ̀hún, kí ó dúró ní ẹnubodè ìlú, kí ó sì ro ẹjọ́ fún àwọn àgbààgbà ibẹ̀. Wọn yóo mú un wọ inú ìlú lọ, wọn yóo fún un ní ibi tí yóo máa gbé, yóo sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 On o si salọ si ọkan ninu ilu wọnni, yio si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na, yio si rò ẹjọ́ rẹ̀ li etí awọn àgba ilu na, nwọn o si gbà a sọdọ sinu ilu na, nwọn o si fun u ni ibi kan, ki o le ma bá wọn gbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Nígbà tí ó bá sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, yóò sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àtiwọ ibodè ìlú, kí ó sì ṣe àlàyé ara rẹ̀ ní iwájú àwọn àgbàgbà ìlú náà. Nígbà náà ni wọn yóò gbà á sí ìlú wọn, wọn yóò sì fun ní ibùgbé láàrín wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 20:4
8 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí mo lọ sí ẹnubodè ìlú, tí mo jókòó ní gbàgede,


Kò sí ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n di àtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹnubodè, kò sì sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n là.


Má pa mí run pẹlu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, má sì gba ẹ̀mí mi pẹlu ti àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìpànìyàn,


Wọ́n dá ọkọ rẹ̀ mọ̀ lẹ́nu ibodè, nígbà tí ó bá jókòó pẹlu àwọn àgbààgbà ìlú.


Nígbà tí Ebedimeleki ará Etiopia tí ó jẹ́ ìwẹ̀fà ní ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremaya sinu kànga. Ọba wà níbi tí ó jókòó sí ní ibodè Bẹnjamini.


Èyí ni pé nípa ohun meji tí kò ṣe é yipada, tí Ọlọrun kò sì lè fi purọ́ ni àwa tí a sá di Ọlọrun fi lè ní ìwúrí pupọ láti di ìlérí tí ó wà níwájú wa mú.


Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan lè sá lọ sibẹ. Ibẹ̀ ni yóo jẹ́ ibi ààbò fun yín tí ọwọ́ ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kò fi ní máa tẹ̀ yín.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan