Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 20:3 - Yoruba Bible

3 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan lè sá lọ sibẹ. Ibẹ̀ ni yóo jẹ́ ibi ààbò fun yín tí ọwọ́ ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kò fi ní máa tẹ̀ yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ki apania ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan li aimọ̀ ki o le salọ sibẹ̀: nwọn o si jẹ́ àbo fun nyin lọwọ olugbẹsan ẹ̀jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 kí ẹni tí ó bá ṣèèṣì pa ènìyàn tàbí tí ó bá pa ènìyàn láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ lè sálọ sí ibẹ̀, fún ààbò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 20:3
8 Iomraidhean Croise  

Obinrin yìí tún wí fún ọba pé, “Kabiyesi, jọ̀wọ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ kí ẹni tí ó fẹ́ gbẹ̀san ikú ọmọ mi kinni má baà pa ọmọ mi keji.” Dafidi ọba bá dáhùn pé, “Mo ṣèlérí fún ọ, ní orúkọ OLUWA Ọlọrun alààyè, pé, ẹnikẹ́ni kò ní ṣe ọmọ rẹ ní ohunkohun.”


sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì ṣe ọ̀kankan ninu ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe, ohun tí wọn óo ṣe nìyí:


Yóo jẹ́ ibi ààbò fún ẹni tí ó paniyan, bí arakunrin ẹni tí ó pa bá fẹ́ gbẹ̀san, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ pa ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan títí yóo fi dúró níwájú ìjọ eniyan Israẹli fún ìdájọ́.


Arakunrin ẹni tí a pa ni yóo pa apànìyàn náà nígbà tí ó bá rí i.


“Ṣugbọn bí ẹnìkan bá ṣèèṣì paniyan, tí kì í ṣe pẹlu ìríra, kì báà jẹ́ pé ó fi ohun ìjà gún un, tabi kí ó ṣèèṣì ju nǹkan lù ú,


Èyí ni pé nípa ohun meji tí kò ṣe é yipada, tí Ọlọrun kò sì lè fi purọ́ ni àwa tí a sá di Ọlọrun fi lè ní ìwúrí pupọ láti di ìlérí tí ó wà níwájú wa mú.


“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n yan àwọn ìlú ààbò tí mo bá Mose sọ nípa rẹ̀, pé kí ó sọ fun yín.


Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan sá lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọ̀hún, kí ó dúró ní ẹnubodè ìlú, kí ó sì ro ẹjọ́ fún àwọn àgbààgbà ibẹ̀. Wọn yóo mú un wọ inú ìlú lọ, wọn yóo fún un ní ibi tí yóo máa gbé, yóo sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan