Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 2:9 - Yoruba Bible

9 “Mo mọ̀ pé OLUWA ti fi ilẹ̀ yìí lé e yín lọ́wọ́, jìnnìjìnnì yín ti bò wá, ẹ̀rù yín sì ti ń ba gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 O si wi fun awọn ọkunrin na pe, Emi mọ̀ pe OLUWA ti fun nyin ni ilẹ yi, ati pe ẹ̀ru nyin bà ni, ati pe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ó sì sọ fún wọn, “Èmi mọ̀ pé Olúwa ti fún un yín ní ilẹ̀ yìí àti pé ẹ̀rù u yín ti sọ wá di ojo dé ibi pé ìdí gbogbo àwọn tí ó n gbé ilẹ̀ yìí ti di omi nítorí i yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 2:9
39 Iomraidhean Croise  

Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn. Jìnnìjìnnì láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sì dà bo gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká wọn, wọn kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu.


Nígbà náà, ẹ̀rù yóo ba àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì láyà bíi kinniun; nítorí pé, gbogbo eniyan ní Israẹli ni ó mọ̀ pé akọni jagunjagun ni baba rẹ, akikanju sì ni àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.


Lẹ́yìn náà ó pada pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ sọ́dọ̀ Eliṣa, ó ní, “Nisinsinyii ni mo mọ̀ pé kò sí ọlọrun mìíràn ní gbogbo ayé àfi Ọlọrun Israẹli. Nítorí náà jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn yìí lọ́wọ́ iranṣẹ rẹ.”


OLUWA ti mú kí àwọn ọmọ ogun Siria gbọ́ ìró ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin ati ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Wọ́n wí fún ara wọn pé ọba Israẹli ti lọ bẹ àwọn ọmọ ogun Hiti ati ti Ijipti láti wá bá àwọn jà.


Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa, ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n, ìtìjú sì mú wọn, nítorí wọ́n mọ̀ pé nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun ni iṣẹ́ náà fi ṣeéṣe.


Ní gbogbo agbègbè, ati ní àwọn ìlú tí ìkéde yìí dé, ìdùnnú ati ayọ̀ kún inú àwọn Juu, wọ́n se àsè pẹlu ayẹyẹ, wọ́n sì gba ìsinmi. Àwọn ẹ̀yà mìíràn sọ ara wọn di Juu, nítorí pé ẹ̀rù àwọn Juu ń bà wọ́n.


Ṣugbọn mo mọ̀ pé Olùdáǹdè mi ń bẹ láàyè, ati pé, níkẹyìn, yóo dìde dúró lórí ilẹ̀ yóo sì jẹ́rìí mi,


Ìbànújẹ́ yóo bá eniyan burúkú nígbà tí ó bá rí i. Yóo pa eyín keke, yóo pòórá, ìfẹ́ rẹ̀ yóo sì di asán.


OLUWA ló ni ọ̀run, ṣugbọn ó fi ayé fún àwọn eniyan.


Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ó ti gba àwọn eniyan náà lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, nígbà tí àwọn ará Ijipti ń lò wọ́n ní ìlò àbùkù ati ẹ̀gàn.”


“N óo da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń lọ dojú ìjà kọ, rúdurùdu yóo sì bẹ́ sí ààrin wọn, gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa sálọ, nígbàkúùgbà tí wọ́n bá gbúròó yín.


Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tilẹ̀ ṣe ibi ní ọpọlọpọ ìgbà tí ọjọ́ rẹ̀ sì gùn, sibẹsibẹ mo mọ̀ pé yóo dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọrun.


Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ijipti nìyí: OLUWA gun ìkùukùu lẹ́ṣin, ó ń yára bọ̀ wá sí Ijipti. Àwọn oriṣa Ijipti yóo máa gbọ̀n níwájú rẹ̀, ọkàn àwọn ará Ijipti yóo sì dàrú.


Nígbà tí ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Tire bá dé Ijipti àwọn ará Ijipti yóo kérora.


òun ni òun fi agbára ńlá òun dá ayé: ati eniyan ati ẹranko tí wọ́n wà lórí ilẹ̀; ẹni tí ó bá tọ́ lójú òun ni òun óo sì fi wọ́n fún.


A ti pa Ninefe run! Ó ti dahoro! Ọkàn àwọn eniyan ti dàrú, orúnkún wọn ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, ìrora dé bá ọpọlọpọ, gbogbo ojú wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.


Mose rán oníṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu pé, “Arakunrin rẹ ni àwa ọmọ Israẹli jẹ́, o sì mọ gbogbo àwọn ìṣòro tí ó ti dé bá wa.


“Níhìn-ín ni Aaroni yóo kú sí, kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí pé n óo fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ̀yin mejeeji lòdì sí àṣẹ mi ní Meriba.


Àbí n kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ohun ìní mi bí mo ti fẹ́? Ṣé ò ń jowú nítorí mo ní inú rere ni?’


Kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo lè dojú kọ yín, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ tí ẹ óo máa rìn kọjá, jìnnìjìnnì yín yóo sì máa bò wọ́n, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.


Láti òní lọ, n óo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé yìí, tí wọ́n bá gbúròó yín, wọn yóo máa gbọ̀n, ojora yóo sì mú wọn nítorí yín.


Gbogbo eniyan ayé ni yóo rí i pé orúkọ OLUWA ni wọ́n fi ń pè ọ́, wọn yóo sì máa bẹ̀rù rẹ.


Nígbà tí Ọlọrun ọ̀gá ògo pín ilẹ̀ ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó ṣètò ibi tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóo máa gbé, gẹ́gẹ́ bí ìdílé kọ̀ọ̀kan láàrin àwọn ọmọ Israẹli.


Nípa igbagbọ ni Rahabu aṣẹ́wó kò fi kú pẹlu àwọn alaigbagbọ, nígbà tí ó ti fi ọ̀yàyà gba àwọn amí.


Bí a ti gbọ́ ni jìnnìjìnnì ti bò wá, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn sì ti bá gbogbo eniyan nítorí yín, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun ọ̀run ati ayé.


Wọ́n sọ fún Joṣua pé, “Láìṣe àní àní, OLUWA ti fi ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́, ìdààmú ọkàn sì ti bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà nítorí wa.”


Kí àwọn amí meji náà tó sùn, Rahabu gun òrùlé lọ bá wọn, ó ní,


Nígbà tí gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Amori, tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, ati gbogbo ọba àwọn ará ilẹ̀ Kenaani, tí wọ́n wà ní etí Òkun gbọ́ pé OLUWA mú kí odò Jọdani gbẹ nítorí àwọn ọmọ Israẹli, títí tí wọ́n fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, àyà wọn já, ìdààmú sì bá wọn, nítorí àwọn ọmọ Israẹli.


OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti fi Jẹriko lé ọ lọ́wọ́ ati ọba wọn ati àwọn akikanju wọn.


ati gbogbo ohun tí ó ṣe sí àwọn ọba Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òdìkejì odò Jọdani, Sihoni ọba àwọn ará Heṣiboni ati Ogu ọba àwọn ará Baṣani tí ń gbé Aṣitarotu.”


Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Wọ́n sọ fún àwa iranṣẹ yín pé, dájúdájú, OLUWA Ọlọrun yín ti pàṣẹ fún Mose láti fun yín ní gbogbo ilẹ̀ yìí, ati láti pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀; nítorí náà ni ẹ̀rù yín ṣe bà wá. Kí ẹ má baà pa wá run ni a fi ṣe ohun tí a ṣe.


Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ọ̀nà jíjìn ni àwa iranṣẹ rẹ ti wá nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, nítorí a ti gbúròó rẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó ṣe sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti,


Ẹnìkejì rẹ̀ dá a lóhùn, ó ní, “Èyí kì í ṣe ohun mìíràn, bíkòṣe idà Gideoni, ọmọ Joaṣi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli. Ọlọrun ti fi Midiani ati gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ lé e lọ́wọ́.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan