Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 2:4 - Yoruba Bible

4 Ṣugbọn obinrin náà ti kó àwọn ọkunrin mejeeji pamọ́, ó dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni àwọn ọkunrin meji kan wá sọ́dọ̀ mi, ṣugbọn n kò mọ ibi tí wọn ti wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Obinrin na si mú awọn ọkunrin meji na, o si fi wọn pamọ́; o si wi bayi pe, Awọn ọkunrin kan wá sọdọ mi, ṣugbọn emi kò mọ̀ ibi ti nwọn ti wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ṣùgbọ́n obìnrin náà ti mú àwọn ọkùnrin méjì náà o sì fi wọ́n pamọ́. Ó sì wí pé, “lóòtítọ́ ní àwọn ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ibi tí wọ́n ti wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 2:4
9 Iomraidhean Croise  

Eliṣa tọ̀ wọ́n lọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣìnà; èyí kì í ṣe ìlú tí ẹ̀ ń wá, ẹ tẹ̀lé mi n óo fi ẹni tí ẹ̀ ń wá hàn yín.” Ó sì mú wọn lọ sí Samaria.


Wọ́n dá Farao lóhùn pé, “Àwọn obinrin Heberu yàtọ̀ sí àwọn obinrin Ijipti. Wọ́n lágbára, wọn a sì ti máa bímọ kí á tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”


Ṣebí bákan náà ni Rahabu aṣẹ́wó gba ìdáláre nípa iṣẹ́, nígbà tí ó ṣe àwọn amí ní àlejò, tí ó jẹ́ kí wọ́n bá ọ̀nà mìíràn pada lọ?


Ọba Jẹriko bá ranṣẹ sí Rahabu ó ní, “Kó àwọn ọkunrin tí wọn dé sọ́dọ̀ rẹ jáde wá, nítorí pé wọ́n wá ṣe amí ilẹ̀ yìí ni.”


Nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè ni wọ́n jáde lọ, n kò sì mọ ibi tí wọ́n lọ. Ẹ tètè máa lépa wọn lọ, ẹ óo bá wọn lọ́nà.”


OLUWA ti yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, àfi Rahabu, aṣẹ́wó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ̀, ni yóo wà láàyè; nítorí òun ni ó gbé àwọn amí tí a rán pamọ́.


Ṣugbọn Joṣua dá Rahabu aṣẹ́wó sí, ati ilé baba rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli títí di òní yìí; nítorí pé, Rahabu ni ó gbé àwọn amí tí Joṣua rán lọ wo ìlú Jẹriko pamọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan