Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 2:3 - Yoruba Bible

3 Ọba Jẹriko bá ranṣẹ sí Rahabu ó ní, “Kó àwọn ọkunrin tí wọn dé sọ́dọ̀ rẹ jáde wá, nítorí pé wọ́n wá ṣe amí ilẹ̀ yìí ni.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ọba Jeriko si ranṣẹ si Rahabu, wipe, Mú awọn ọkunrin nì ti o tọ̀ ọ wá, ti o wọ̀ inu ile rẹ jade wá: nitori nwọn wá lati rìn gbogbo ilẹ yi wò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ọba Jeriko sì ránṣẹ́ sí Rahabu pé: “Mú àwọn ọkùnrin nì tí ó tọ̀ ọ́ wá, tí ó wọ inú ilé rẹ jáde wá, nítorí wọ́n wá láti yọ́ gbogbo ilẹ̀ yìí wò ni.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 2:3
15 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn bí oṣù mẹta sí i, ẹnìkan wá sọ fún Juda pé, “Wò ó! Iṣẹ́ aṣẹ́wó ni Tamari, opó ọmọ rẹ ń ṣe, ó sì ti lóyún.” Juda bá dáhùn, ó ní, “Ẹ lọ mú un wá kí wọ́n dáná sun ún.”


Ṣugbọn a wí fún un pé, ‘Olóòótọ́ ni wá, a kì í ṣe eniyankeniyan, ati pé a kì í ṣe amí rárá.


àwọn àgbààgbà ìlú náà wí fún Hanuni ọba wọn pé, “Ṣé o rò pé baba rẹ ni Dafidi bu ọlá fún tóbẹ́ẹ̀, tí ó fi rán àwọn oníṣẹ́ láti wá tù ọ́ ninu? Rárá o! Amí ni ó rán wọn wá ṣe, kí wọ́n lè wo gbogbo ìlú wò, kí ó baà lè ṣẹgun wa.”


Nígbà tí àwọn iranṣẹ Absalomu dé ọ̀dọ̀ obinrin náà, wọ́n bi í pé, “Níbo ni Ahimaasi ati Jonatani wà?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti kọjá sí òdìkejì odò.” Àwọn ọkunrin náà wá wọn títí, ṣugbọn wọn kò rí wọn. Wọ́n bá pada lọ sí Jerusalẹmu.


Ṣugbọn àwọn ìjòyè ilẹ̀ Amoni sọ fún ọba pé, “Ṣé o rò pé Dafidi ń bọ̀wọ̀ fún baba rẹ ni ó ṣe rán oníṣẹ́ láti wá bá ọ kẹ́dùn? Rárá o. Ó rán wọn láti wá ṣe amí ilẹ̀ yìí ni, kí ó baà lè ṣẹgun rẹ.”


a dá ẹni ibi sí ní ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀, ati pé a gbà á là ní ọjọ́ ibinu?


“Mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, kí gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ nígbà tí ó ṣépè gbé ọwọ́ lé e lórí, kí gbogbo ìjọ eniyan sì sọ ọ́ ní òkúta pa.


Pilatu tún jáde lọ sóde, ó sọ fún àwọn Juu pé, “Mò ń mú un tọ̀ yín bọ̀ wá sóde, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí i pé ó jẹ̀bi ohunkohun.”


Ó bá mú Peteru ó tì í mọ́lé. Ó fi í lé àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun mẹrin lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ; (ọmọ-ogun mẹrin ni ó wà ní ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan). Hẹrọdu fẹ́ mú Peteru wá siwaju gbogbo eniyan fún ìdájọ́ lẹ́yìn Àjọ̀dún Ìrékọjá.


Ní òru, mọ́jú ọjọ́ tí Hẹrọdu ìbá mú Peteru wá fún ìdájọ́, Peteru sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun meji, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é; àwọn ọmọ-ogun kan sì tún wà lẹ́nu ọ̀nà, tí wọn ń ṣọ́nà.


Wọ́n bá kó wọn jáde, láti inú ihò: ọba Jerusalẹmu, ọba Heburoni, ọba Jarimutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egiloni.


Àwọn kan bá lọ sọ fún ọba Jẹriko pé, “Àwọn ọkunrin kan, lára àwọn ọmọ Israẹli, wá sí ibí ní alẹ́ yìí láti ṣe amí ilẹ̀ yìí.”


Ṣugbọn obinrin náà ti kó àwọn ọkunrin mejeeji pamọ́, ó dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni àwọn ọkunrin meji kan wá sọ́dọ̀ mi, ṣugbọn n kò mọ ibi tí wọn ti wá.


Sisera wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá wá, tí ó sì bi ọ́ léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wà níbí?’ Wí fún olúwarẹ̀ pé, ‘Kò sí.’ ”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan