Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 2:12 - Yoruba Bible

12 Nítorí náà, ẹ fi OLUWA búra fún mi nisinsinyii pé, bí mo ti ṣe yín lóore yìí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ṣe ilé baba mi lóore, kí ẹ sì fún mi ní àmì tí ó dájú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Njẹ nitorina, emi bẹ̀ nyin, ẹ fi OLUWA bura fun mi, bi mo ti ṣe nyin li ore, ẹnyin o ṣe ore pẹlu fun ile baba mi, ẹnyin o si fun mi li àmi otitọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ búra fún mi ní ti Olúwa pé ẹ̀yin yóò ṣe àánú fún ìdílé mi, nítorí pé mo ti ṣe yín ní oore. Ẹ̀yin yóò fún mi ní ààmì tó dájú:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 2:12
24 Iomraidhean Croise  

Nítorí náà, fi Ọlọrun búra fún mi níhìn-ín yìí, pé o kò ní hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi, tabi sí àwọn ọmọ mi, tabi sí ìran mi, ṣugbọn bí mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ náà yóo jẹ́ olóòótọ́ sí mi ati sí ilẹ̀ tí o ti ń ṣe àtìpó.”


n óo sì mú kí o búra ní orúkọ OLUWA Ọlọrun ọ̀run ati ayé, pé o kò ní fẹ́ aya fún ọmọ mi lára àwọn ọmọbinrin ará Kenaani tí mò ń gbé,


Iranṣẹ náà bá ti ọwọ́ rẹ̀ bọ abẹ́ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, ó sì búra láti ṣe ohun tí Abrahamu pa láṣẹ fún un.


Ṣugbọn ṣá o, ranti mi nígbà tí ó bá dára fún ọ, jọ̀wọ́, ṣe mí lóore kan, ròyìn mi fún Farao, kí Farao sì yọ mí kúrò ninu àhámọ́ yìí.


Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinesari, bẹ́ẹ̀ sì ni Nebukadinesari ti fi ipá mú un búra ní orúkọ OLUWA pé kò ní ṣọ̀tẹ̀ sí òun. Ó ṣoríkunkun, ó sì kọ̀ láti yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli.


Mo ṣe lè rí jamba tí ń bọ̀, tabi ìparun tí ń bọ̀ sórí àwọn eniyan mi, kí n sì dákẹ́?”


Ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá fi kun àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn gbogbo ilé yín ni yóo jẹ́ àmì láti fi gbogbo ibi tí ẹ bá wà hàn. Nígbà tí mo bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, n óo re yín kọjá; n kò ní fi àjàkálẹ̀ àrùn ba yín jà láti pa yín run nígbà tí mo bá ń jẹ àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti níyà.


Nígbà tí ó bá yá, bí wọ́n bá fi tọkàntọkàn kọ́ àṣà àwọn eniyan mi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ mi búra, tí wọn ń wí pé, ‘Bí OLUWA Ọlọrun ti wà láàyè’, bí àwọn náà ṣe kọ́ àwọn eniyan mi láti máa fi orúkọ Baali búra, n óo fi ìdí wọn múlẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi.


Ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá ti fi àmì fún wọn. Ó ní, “Ẹni tí mo bá kí, tí mo fi ẹnu kàn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ọkunrin náà. Ẹ mú un, kí ẹ fà á lọ, ẹ má jẹ́ kí ó bọ́.”


wọn kò sì ní ẹ̀rí ọkàn. Aláìṣeégbẹ́kẹ̀lé ni wọ́n, aláìnífẹ̀ẹ́, ati aláìláàánú.


Bí ẹnìkan kò bá pèsè fún àwọn ẹbí rẹ̀, pataki jùlọ fún àwọn ìdílé rẹ̀, olúwarẹ̀ ti lòdì sí ẹ̀sìn igbagbọ wa, ó sì burú ju alaigbagbọ lọ.


Nítorí kò ní sí àánú ninu ìdájọ́ fún àwọn tí kò ní ojú àánú, bẹ́ẹ̀ sì ni àánú ló borí ìdájọ́.


Kí ẹ dá baba mi ati ìyá mi sí, ati àwọn arakunrin mi, ati àwọn arabinrin mi, ati gbogbo àwọn eniyan wọn; ẹ má jẹ́ kí á kú.”


Nígbà tí a bá wọ ilẹ̀ yìí, mú okùn pupa yìí, kí o so ó mọ́ ibi fèrèsé tí o ti sọ̀ wá kalẹ̀. Kó baba, ati ìyá rẹ, ati àwọn arakunrin rẹ, ati gbogbo àwọn ará ilé baba rẹ sí inú ilé rẹ.


Bí ẹnikẹ́ni bá jáde kúrò ninu ilé rẹ lọ sí ààrin ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí ara rẹ̀, kò sì ní sí ẹ̀bi lọ́rùn wa. Ṣugbọn bí wọn bá pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí wa.


Joṣua sọ fún àwọn ọkunrin meji tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà pé, “Ẹ wọ ilé aṣẹ́wó náà lọ, kí ẹ sì mú obinrin náà wá ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti búra fún un.”


Joṣua bá wọn dá majẹmu alaafia, pé, àwọn kò ní pa wọ́n, àwọn àgbààgbà Israẹli sì búra fún wọn.


Àwọn amí náà rí ọkunrin kan tí ń jáde bọ̀ láti inú ìlú náà, wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, fi ọ̀nà tí a óo gbà wọ ìlú yìí hàn wá, a óo sì ṣe ọ́ lóore.”


Dafidi bi í léèrè pé, “Ṣé o lè mú mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ogun náà?” Ó dáhùn pé, “N óo mú ọ lọ, bí o bá ṣèlérí ní orúkọ Ọlọrun pé o kò ní pa mí, tabi kí o fi mí lé oluwa mi lọ́wọ́.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan