Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 2:11 - Yoruba Bible

11 Bí a ti gbọ́ ni jìnnìjìnnì ti bò wá, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn sì ti bá gbogbo eniyan nítorí yín, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun ọ̀run ati ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Lọgán bi awa ti gbọ́ nkan wọnyi, àiya wa já, bẹ̃ni kò si sí agbara kan ninu ọkunrin kan mọ́ nitori nyin; nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li Ọlọrun loke ọrun, ati nisalẹ aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Bí a ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ọkàn wa pami kò sì sí okun kankan fún wa mọ́ nítorí i yín, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti ní ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 2:11
27 Iomraidhean Croise  

kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé lè mọ̀ pé OLUWA ni Ọlọrun, ati pé kò sí ẹlòmíràn mọ́.


Lẹ́yìn náà ó pada pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ sọ́dọ̀ Eliṣa, ó ní, “Nisinsinyii ni mo mọ̀ pé kò sí ọlọrun mìíràn ní gbogbo ayé àfi Ọlọrun Israẹli. Nítorí náà jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn yìí lọ́wọ́ iranṣẹ rẹ.”


Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa, ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n, ìtìjú sì mú wọn, nítorí wọ́n mọ̀ pé nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun ni iṣẹ́ náà fi ṣeéṣe.


Ní gbogbo agbègbè, ati ní àwọn ìlú tí ìkéde yìí dé, ìdùnnú ati ayọ̀ kún inú àwọn Juu, wọ́n se àsè pẹlu ayẹyẹ, wọ́n sì gba ìsinmi. Àwọn ẹ̀yà mìíràn sọ ara wọn di Juu, nítorí pé ẹ̀rù àwọn Juu ń bà wọ́n.


Àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo sì máa bẹ̀rù ògo rẹ̀.


Agbára mi ti lọ, ó ti ṣàn dànù bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ lóríkèéríkèé; ọkàn mi dàbí ìda, ó ti yọ́.


Jẹ́ kí wọ́n rá, kí wọn ṣàn lọ bí omi; kí á tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi koríko, kí wọn sì rọ.


Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ nìkan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA, ni Ọ̀gá Ògo lórí gbogbo ayé.


Àwọn eniyan ti gbọ́, wọ́n wárìrì, jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ Filistini.


Ẹnu ya àwọn ìjòyè Edomu, ojora sì mú gbogbo àwọn olórí ní ilẹ̀ Moabu, gbogbo àwọn tí ń gbé Kenaani sì ti kú sára.


Nítorí náà ọwọ́ gbogbo eniyan yóo rọ, ọkàn gbogbo eniyan yóo rẹ̀wẹ̀sì;


Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ijipti nìyí: OLUWA gun ìkùukùu lẹ́ṣin, ó ń yára bọ̀ wá sí Ijipti. Àwọn oriṣa Ijipti yóo máa gbọ̀n níwájú rẹ̀, ọkàn àwọn ará Ijipti yóo sì dàrú.


Kí àyà wọn lè já, kí ọpọlọpọ lè kú ní ẹnubodè wọn. Mo ti fi idà tí ń dán lélẹ̀ fún pípa eniyan, ó ń kọ mànà bíi mànàmáná, a sì ti fi epo pa á.


A ti pa Ninefe run! Ó ti dahoro! Ọkàn àwọn eniyan ti dàrú, orúnkún wọn ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, ìrora dé bá ọpọlọpọ, gbogbo ojú wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.


Kí ni a fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀? Ojora ti mú wa, nítorí ọ̀rọ̀ tí àwọn arakunrin wa sọ fún wa, tí wọ́n ní àwọn ará ibẹ̀ lágbára jù wá lọ, wọ́n sì ṣígbọnlẹ̀ jù wá lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, odi wọn ga kan ọ̀run, àwọn òmìrán ọmọ Anaki sì wà níbẹ̀!’


“Àwọn ọ̀gágun yóo tún bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ẹ̀rù ń bà, tabi tí àyà rẹ̀ ń já? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé, kí ó má baà kó ojora bá àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.’


Kí ẹ mọ̀ lónìí, kí ó sì da yín lójú pé, OLUWA ni Ọlọrun; kò sí ọlọrun mìíràn mọ́ ní ọ̀run ati ní ayé.


Ṣugbọn àwọn arakunrin mi tí a jọ lọ dáyàjá àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun mi.


Wọ́n sọ fún Joṣua pé, “Láìṣe àní àní, OLUWA ti fi ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́, ìdààmú ọkàn sì ti bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà nítorí wa.”


Nígbà tí gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Amori, tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, ati gbogbo ọba àwọn ará ilẹ̀ Kenaani, tí wọ́n wà ní etí Òkun gbọ́ pé OLUWA mú kí odò Jọdani gbẹ nítorí àwọn ọmọ Israẹli, títí tí wọ́n fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, àyà wọn já, ìdààmú sì bá wọn, nítorí àwọn ọmọ Israẹli.


Àwọn ọmọ ogun Ai pa tó mẹrindinlogoji (36) ninu wọn, wọ́n sì lé gbogbo wọn kúrò ní ẹnubodè wọn títí dé Ṣebarimu. Wọ́n ń pa àwọn ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà. Ọkàn àwọn ọmọ Israẹli bá dààmú, àyà wọn sì já.


Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Wọ́n sọ fún àwa iranṣẹ yín pé, dájúdájú, OLUWA Ọlọrun yín ti pàṣẹ fún Mose láti fun yín ní gbogbo ilẹ̀ yìí, ati láti pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀; nítorí náà ni ẹ̀rù yín ṣe bà wá. Kí ẹ má baà pa wá run ni a fi ṣe ohun tí a ṣe.


Wọ́n ń sọ fún àwọn òkè ati àpáta pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ pa wá mọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ati ibinu Ọ̀dọ́ Aguntan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan