Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 17:9 - Yoruba Bible

9 Ààlà ilẹ̀ wọn tún lọ sí apá ìsàlẹ̀ títí dé odò Kana, àwọn ìlú wọnyi tí wọ́n wà ní apá gúsù odò náà, láàrin ìlú àwọn ọmọ Manase, jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu. Ààlà àwọn ọmọ Manase tún lọ sí apá àríwá odò náà, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Àla rẹ̀ si sọkalẹ lọ si odò Kana, ni ìha gusù odò na: ilu Efraimu wọnyi wà lãrin awọn ilu Manasse: àla Manasse pẹlu si wà ni ìha ariwa odò na, o si yọ si okun:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ààlà rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ odò Kana, ní ìhà gúúsù odò náà. Àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti Efraimu wà ní àárín àwọn ìlú Manase, ṣùgbọ́n ààlà Manase ni ìhà àríwá odò náà, ó sì yọ sí Òkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 17:9
4 Iomraidhean Croise  

Bákan náà ni ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn títí dé agbègbè àwọn ará Jafileti, títí dé apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni. Ó tún lọ láti ibẹ̀ títí dé Geseri, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia.


Ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìhà gúsù jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu, èyí tí ó wà ní apá ìhà àríwá jẹ́ ti àwọn ọmọ Manase. Òkun Mẹditarenia ni ààlà wọn ní apá ìwọ̀ oòrùn. Ní apá ìhà àríwá, ilẹ̀ wọn lọ títí kan ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, ó sì kan ti ẹ̀yà Isakari ní apá ìlà oòrùn.


Lẹ́yìn náà, ààlà náà yípo lọ sí Rama; ó dé ìlú olódi ti Tire, lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí Hosa, ó sì pin sí etíkun. Ninu ilẹ̀ wọn ni Mahalabu, Akisibu;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan