Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 17:4 - Yoruba Bible

4 Wọ́n tọ Eleasari, alufaa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati àwọn àgbààgbà lọ, wọ́n wí fún wọn pé, “OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí ó pín ilẹ̀ fún àwa náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti pín fún àwọn ìbátan wa, tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.” Nítorí náà bí OLUWA ti pa á láṣẹ, wọ́n pín ilẹ̀ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pín fún àwọn ìbátan wọn tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Nwọn si wá siwaju Eleasari alufa, ati siwaju Joṣua ọmọ Nuni, ati siwaju awọn olori, wipe, OLUWA fi aṣẹ fun Mose lati fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin wa: nitorina o fi ilẹ-iní fun wọn lãrin awọn arakunrin baba wọn, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Wọ́n sì lọ bá Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni, àti àwọn olórí wí pé, “Olúwa pàṣẹ fún Mose láti fún wa ní ìní ní àárín àwọn arákùnrin wa.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua fún wọn ní ìní pẹ̀lú àwọn arákùnrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 17:4
9 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Mahila, Noa, Hogila, Milika ati Tirisa, àwọn ọmọbinrin Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, ti ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu,


Kí ló dé tí orúkọ baba wa yóo fi parẹ́ kúrò ninu ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkunrin? Nítorí náà, ẹ fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrin àwọn eniyan baba wa.”


Àwọn ọmọbinrin Selofehadi ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA fún Mose;


Kò tún sí ọ̀rọ̀ pé ẹnìkan ni Juu, ẹnìkan ni Giriki mọ́, tabi pé ẹnìkan jẹ́ ẹrú tabi òmìnira, ọkunrin tabi obinrin. Nítorí gbogbo yín ti di ọ̀kan ninu Kristi Jesu.


Àkọsílẹ̀ bí wọn ṣe pín ilẹ̀ Kenaani, tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani fún àwọn ọmọ Israẹli nìyí. Eleasari alufaa, Joṣua, ọmọ Nuni, ati àwọn olórí láti inú ìdílé kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe ètò pípín ilẹ̀ náà.


Ìdí nìyí tí ìpín mẹ́wàá fi kan Manase láìka Gileadi, ati Baṣani ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani.


Lẹ́yìn náà àwọn olórí ìdílé ninu ẹ̀yà Lefi wá sí ọ̀dọ̀ Eleasari alufaa, ati sí ọ̀dọ̀ Joṣua ọmọ Nuni, ati àwọn olórí ìdílé ní gbogbo ẹ̀yà Israẹli,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan