Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 17:2 - Yoruba Bible

2 Wọ́n fún àwọn ìdílé Manase yòókù ní ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn: àwọn bíi Abieseri, Heleki, Asirieli, Ṣekemu, Heferi, ati Ṣemida. Àwọn ni ọmọkunrin Manase, tíí ṣe ọmọ Josẹfu; wọ́n sì jẹ́ olórí fún àwọn ìdílé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Awọn ọmọ Manasse iyokù si ní ilẹ-iní gẹgẹ bi idile wọn; awọn ọmọ Abieseri, ati awọn ọmọ Heleki, ati awọn ọmọ Asrieli, ati awọn ọmọ Ṣekemu, ati awọn ọmọ Heferi, ati awọn ọmọ Ṣemida: awọn wọnyi ni awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nítorí náà ìpín yìí wà fún ìyókù àwọn ènìyàn Manase: ní agbo ilé Abieseri, Heleki, Asrieli, Ṣekemu, Heferi àti Ṣemida. Ìwọ̀nyí ní àwọn ọmọ ọkùnrin Manase ọmọ Josẹfu ní agbo ilé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 17:2
6 Iomraidhean Croise  

Arabinrin Gileadi kan tí ń jẹ́ Hamoleketu ni ó bí Iṣodu, Abieseri, ati Mahila.


Wọ́n pín ilẹ̀ fún ẹ̀yà Manase nítorí pé ó jẹ́ àkọ́bí Josẹfu. Makiri, baba Gileadi, tí ó jẹ́ àkọ́bí Manase ni wọ́n fún ní ilẹ̀ Gileadi ati Baṣani nítorí pé ó jẹ́ akọni ati akikanju eniyan.


Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkunrin rárá, àfi kìkì ọmọbinrin. Orúkọ wọn ni Mahila, Noa, Hogila, Milika, ati Tirisa.


Angẹli OLUWA kan wá, ó jókòó lábẹ́ igi Oaku tí ó wà ní Ofira, igi Oaku yìí jẹ́ ti Joaṣi, ará Abieseri. Bí Gideoni ọmọ Joaṣi, ti ń pa ọkà ní ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí, tí ó ń fi í pamọ́ fún àwọn ará Midiani,


Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Kí ni mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe? Ohun tí ẹ̀yin ará Efuraimu ṣe, tí ẹ rò pé ohun kékeré ni yìí, ó ju gbogbo ohun tí àwọn ará Abieseri ṣe, tí ẹ kà kún nǹkan bàbàrà lọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan