Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 17:1 - Yoruba Bible

1 Wọ́n pín ilẹ̀ fún ẹ̀yà Manase nítorí pé ó jẹ́ àkọ́bí Josẹfu. Makiri, baba Gileadi, tí ó jẹ́ àkọ́bí Manase ni wọ́n fún ní ilẹ̀ Gileadi ati Baṣani nítorí pé ó jẹ́ akọni ati akikanju eniyan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 EYI si ni ipín ẹ̀ya Manasse; nitori on li akọ́bi Josefu. Bi o ṣe ti Makiri akọ́bi Manasse, baba Gileadi, nitori on ṣe ologun, nitorina li o ṣe ní Gileadi ati Baṣani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Èyí ní ìpín ẹ̀yà Manase tí í ṣe àkọ́bí Josẹfu, fún Makiri, àkọ́bí Manase. Makiri sì ni baba ńlá àwọn ọmọ Gileadi, tí ó ti gba Gileadi àti Baṣani nítorí pé àwọn ọmọ Makiri jẹ́ jagunjagun ńlá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 17:1
20 Iomraidhean Croise  

Josẹfu sọ ọmọ rẹ̀ kinni ní Manase, ó ní, “Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìnira mi ati ilé baba mi.”


Ó sọ ọmọ keji ní Efuraimu, ó ní, “Ọlọrun ti mú mi bí sí i ní ilẹ̀ tí mo ti rí ìpọ́njú.”


Asenati, ọmọbinrin Pọtifera bí Manase ati Efuraimu fún Josẹfu ní ilẹ̀ Ijipti. Pọtifera ni babalóòṣà oriṣa Oni, ní Ijipti.


Nígbà tí Josẹfu rí i pé ọwọ́ ọ̀tún ni baba òun gbé lé Efuraimu lórí, kò dùn mọ́ ọn. Ó bá di ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé e kúrò lórí Efuraimu kí ó sì gbé e lórí Manase.


Ó wí fún baba rẹ̀ pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, baba, eléyìí ni àkọ́bí, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé e lórí.”


Josẹfu rí ìran kẹta ninu àwọn ọmọ Efuraimu. Àwọn ọmọ tí Makiri ọmọ Manase bí, ọwọ́ Josẹfu ni ó bí wọn sí pẹlu.


Níbẹ̀ ni ó ti fi Iṣiboṣẹti jọba lórí gbogbo agbègbè Gileadi, Aṣuri, Jesireeli, Efuraimu, Bẹnjamini, ati lórí gbogbo ilẹ̀ Israẹli.


Ṣugbọn Geṣuri ati Aramu gba Hafoti Jairi lọ́wọ́ rẹ̀, ati Kenati ati àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká rẹ̀; gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Makiri, baba Gileadi.


OLUWA Ọlọrun ní, “Èyí ni yóo jẹ́ ààlà tí ẹ óo fi pín ilẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Josẹfu yóo ní ìpín meji;


Ìpín ti Manase yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Nafutali, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn,


Àwọn ọmọ Manase ni: ìdílé Makiri, Makiri bí Gileadi.


Nígbà náà ni Mahila, Noa, Hogila, Milika ati Tirisa, àwọn ọmọbinrin Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, ti ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu,


Mose bá fi ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori, ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani ati àwọn ilẹ̀ ati àwọn ìlú tí ó yí wọn ká fún àwọn ọmọ Gadi, àwọn ọmọ Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu.


Ṣugbọn kí ó fihàn pé ọmọ obinrin tí òun kò fẹ́ràn yìí ni àkọ́bí òun, kí ó sì fún un ní ogún tí ó tọ́ sí i ninu ohun ìní rẹ̀. Òun ṣá ni àkọ́bí rẹ̀, òun sì ni ẹ̀tọ́ àkọ́bí tọ́ sí.


Wọ́n fún àwọn ìdílé Manase yòókù ní ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn: àwọn bíi Abieseri, Heleki, Asirieli, Ṣekemu, Heferi, ati Ṣemida. Àwọn ni ọmọkunrin Manase, tíí ṣe ọmọ Josẹfu; wọ́n sì jẹ́ olórí fún àwọn ìdílé wọn.


Mose ti kọ́kọ́ fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ ní Baṣani; Joṣua sì fún ìdajì yòókù ní ilẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ti àwọn arakunrin wọn, ní ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani. Nígbà tí Joṣua rán wọn pada lọ sí ilé wọn, tí ó sì súre fún wọn, ó wí fún wọn pé,


Wọ́n gbéra láti Efuraimu lọ sí àfonífojì náà, wọ́n tẹ̀lé ọ, ìwọ Bẹnjamini pẹlu àwọn eniyan rẹ. Àwọn ọ̀gágun wá láti Makiri, àwọn olórí ogun sì wá láti Sebuluni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan