Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 16:9 - Yoruba Bible

9 pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò wọn tí ó wà ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Manase, ṣugbọn tí a fi fún ẹ̀yà Efuraimu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Pẹlu ilu ti a yàsọtọ fun awọn ọmọ Efraimu lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Manasse, gbogbo ilu na pẹlu ileto wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ó tún mú àwọn ìlú àti ìletò wọn tí ó yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Efraimu tí ó wà ní àárín ìní àwọn ọmọ Manase.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 16:9
6 Iomraidhean Croise  

Níbẹ̀ ni ó ti fi Iṣiboṣẹti jọba lórí gbogbo agbègbè Gileadi, Aṣuri, Jesireeli, Efuraimu, Bẹnjamini, ati lórí gbogbo ilẹ̀ Israẹli.


Àwọn ilẹ̀ ìní wọn ati àwọn agbègbè tí wọ́n tẹ̀dó sí nìwọ̀nyí: Bẹtẹli, Naarani ní apá ìlà oòrùn, Geseri ní apá ìwọ̀ oòrùn, Ṣekemu ati Aya; pẹlu àwọn ìletò tí ó wà lẹ́bàá àyíká wọn.


Ìpín ti Efuraimu yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Manase, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.


Ṣugbọn wọn kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Geseri jáde, nítorí náà, àwọn ará Kenaani ń gbé ààrin ẹ̀yà Efuraimu títí di òní olónìí. Ẹ̀yà Efuraimu ń fi tipátipá mú wọn ṣiṣẹ́ bí ẹrú.


Láti Tapua, ààlà náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé odò Kana, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Èyí ni ilẹ̀ tí wọ́n pín fún ẹ̀yà Efuraimu gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn,


Ààlà ilẹ̀ wọn tún lọ sí apá ìsàlẹ̀ títí dé odò Kana, àwọn ìlú wọnyi tí wọ́n wà ní apá gúsù odò náà, láàrin ìlú àwọn ọmọ Manase, jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu. Ààlà àwọn ọmọ Manase tún lọ sí apá àríwá odò náà, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan