Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 16:4 - Yoruba Bible

4 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Josẹfu, tí à ń pè ní ẹ̀yà Manase ati ẹ̀yà Efuraimu ṣe gba ìpín tiwọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Bẹ̃li awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu, gbà ilẹ-iní wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Báyìí ni Manase àti Efraimu, àwọn ọmọ Josẹfu, gba ilẹ̀ ìní wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 16:4
6 Iomraidhean Croise  

Ó sọ ọmọ keji ní Efuraimu, ó ní, “Ọlọrun ti mú mi bí sí i ní ilẹ̀ tí mo ti rí ìpọ́njú.”


OLUWA Ọlọrun ní, “Èyí ni yóo jẹ́ ààlà tí ẹ óo fi pín ilẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Josẹfu yóo ní ìpín meji;


Meji ni wọ́n pín àwọn ẹ̀yà Josẹfu sí, àwọn ìpín mejeeji náà ni ẹ̀yà Manase ati ti Efuraimu. Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ìpín kankan ninu ilẹ̀ náà, ṣugbọn wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú láti máa gbé, ati pápá, ibi tí wọ́n ti lè máa da mààlúù wọn, ati gbogbo ẹran ọ̀sìn tí wọ́n ní.


Èyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Efuraimu gbà, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ààlà ilẹ̀ wọn ní apá ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ láti Atarotu Adari, títí dé apá òkè Beti Horoni.


Àwọn ẹ̀yà Josẹfu lọ bá Joṣua, wọ́n wí fún un pé, “Kí ló dé tí o fi fún wa ní ẹyọ ilẹ̀ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwa, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn eniyan wa pọ̀ gan-an, nítorí pé OLUWA ti bukun wa?”


Ọ̀nà meje ni wọn yóo pín ilẹ̀ náà sí, àwọn ẹ̀yà Juda kò ní kúrò ní àyè tiwọn ní apá ìhà gúsù, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀yà Josẹfu tí wọ́n wà ní agbègbè tiwọn ní apá ìhà àríwá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan