Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 16:3 - Yoruba Bible

3 Bákan náà ni ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn títí dé agbègbè àwọn ará Jafileti, títí dé apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni. Ó tún lọ láti ibẹ̀ títí dé Geseri, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 O si sọkalẹ ni ìha ìwọ-õrùn si àgbegbe Jafleti, dé àgbegbe Beti-horoni isalẹ, ani dé Geseri: o si yọ si okun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn agbègbè àwọn ará Jefileti, títí dé ilẹ̀ ìsàlẹ̀ Beti-Horoni, àní dé Geseri, ó sì parí sí etí Òkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 16:3
9 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn náà, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Geseri, láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Sibekai, ará Huṣati, pa ìran òmìrán kan, ará Filistia, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sipai, àwọn ará Israẹli bá ṣẹgun àwọn ará Filistia.


Efuraimu ní ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣeera, òun ló kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati ti ìsàlẹ̀, ati Useni Ṣeera.


Àwọn ilẹ̀ ìní wọn ati àwọn agbègbè tí wọ́n tẹ̀dó sí nìwọ̀nyí: Bẹtẹli, Naarani ní apá ìlà oòrùn, Geseri ní apá ìwọ̀ oòrùn, Ṣekemu ati Aya; pẹlu àwọn ìletò tí ó wà lẹ́bàá àyíká wọn.


Ó kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati Beti Horoni ti ìsàlẹ̀. Wọ́n jẹ́ ìlú olódi, wọ́n ní ìlẹ̀kùn ati ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn,


“Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Òkun ni yóo jẹ́ ààlà yín.


Horamu ọba Geseri wá láti ran àwọn ará ìlú Lakiṣi lọ́wọ́, Joṣua gbógun tì í, ó sì pa òun ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ láìku ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo.


Láti ibẹ̀ ààlà ilẹ̀ náà gba apá ìhà gúsù, ní ọ̀nà Lusi, kọjá lọ sí ara òkè, (Lusi ni wọ́n ń pè ní Bẹtẹli tẹ́lẹ̀) ààlà náà tún yípo lọ sí apá ìsàlẹ̀, sí ọ̀nà Atarotu Adari, sí orí òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù, ni ìsàlẹ̀ Beti Horoni.


àwọn kan lọ sí apá ọ̀nà Beti Horoni, àwọn yòókù lọ sí ẹ̀bá ìpínlẹ̀ àtiwọ àfonífojì Seboimu ní ọ̀nà aṣálẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan