Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 16:1 - Yoruba Bible

1 Ààlà ilẹ̀ tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Josẹfu bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọdani lẹ́bàá Jẹriko, ní apá ìlà oòrùn àwọn odò Jẹriko, ó lọ títí dé apá aṣálẹ̀. Ó tún bẹ̀rẹ̀ láti Jẹriko lọ sí apá àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, títí dé Bẹtẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 IPÍN awọn ọmọ Josefu yọ lati Jordani lọ ni Jeriko, ni omi Jeriko ni ìha ìla-õrùn, ani aginjù, ti o gòke lati Jeriko lọ dé ilẹ òke Beti-eli;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ìpín ti àwọn ọmọ Josẹfu láti Jordani lẹ́bàá Jeriko, ní omi Jeriko ní ìhà ìlà-oòrùn, àní aginjù, tí ó gòkè láti Jeriko lọ dé ilẹ̀ òkè Beteli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 16:1
10 Iomraidhean Croise  

Àwọn tí Rakẹli bí ni: Josẹfu ati Bẹnjamini.


Ìpín ti Efuraimu yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Manase, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.


Àwọn ìlú tí wọ́n wà ní aṣálẹ̀ ni, Betaraba, Midini, Sekaka;


Ní apá ìhà àríwá, ààlà ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ ní etí odò Jọdani, lọ sí ara òkè ní ìhà àríwá Jẹriko. Ó gba ààrin àwọn ìlú tí wọ́n wà ní orí òkè lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì pin sí aṣálẹ̀ Betafeni.


Ọ̀nà meje ni wọn yóo pín ilẹ̀ náà sí, àwọn ẹ̀yà Juda kò ní kúrò ní àyè tiwọn ní apá ìhà gúsù, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀yà Josẹfu tí wọ́n wà ní agbègbè tiwọn ní apá ìhà àríwá.


Joṣua ati gbogbo ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá ṣe bí ẹni pé àwọn ará Ai ti ṣẹgun àwọn, wọ́n sì sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ.


Àwọn ọmọ Josẹfu náà gbógun ti ìlú Bẹtẹli, OLUWA sì wà pẹlu wọn.


Wọ́n rán àwọn amí láti lọ wo Bẹtẹli. (Lusi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀.)


Ó fi ranṣẹ sí àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli, ati àwọn tí wọ́n wà ní Ramoti ti Nẹgẹbu, ati Jatiri;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan