Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 15:3 - Yoruba Bible

3 láti apá etí òkun tí ó kọjú sí ìhà gúsù lọ títí dé àtigun òkè Akirabimu. Ó lọ títí dé Sini, ó tún lọ sí apá gúsù Kadeṣi Banea. Ó kọjá lọ lẹ́bàá Hesironi títí dé Adari, kí ó tó wá yípo lọ sí ìhà Kaka.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 O si lọ si apa gusù òke Akrabbimu, o si lọ si Sini, o si gòke lọ ni ìha gusù Kadeṣi-barnea, o si lọ ni ìha Hesroni, o si gòke lọ si Adari, o si yiká lọ dé Karka:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ó sì gba gúúsù Akrabbimu lọ, títí dé Sini àti sí iwájú ìhà gúúsù Kadeṣi-Barnea. Nígbà náà ó sì tún kọjá Hesroni lọ sí Adari, ó sì tún yípo yíká lọ sí Karka.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 15:3
7 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni wọ́n tó yipada tí wọ́n sì wá sí Enmiṣipati (tí ó tún ń jẹ́ Kadeṣi), wọ́n sì ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amaleki ati ti àwọn ará Amori tí ń gbé Hasasoni Tamari.


Ní oṣù kinni, àwọn ọmọ Israẹli dé aṣálẹ̀ Sini, wọ́n sì ṣe ibùdó wọn sí Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú sí, tí wọn sì sin ín sí.


Bẹ́ẹ̀ ni àwọn baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi Banea láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà.


Yóo sì yí láti ìhà gúsù lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Akirabimu, yóo sì la aṣálẹ̀ Sini kọjá lọ títí dé ìhà gúsù Kadeṣi Banea ati títí dé Hasari Adari ati títí dé Asimoni.


Ààlà ilẹ̀ wọn, ní ìhà gúsù lọ láti òpin Òkun Iyọ̀,


Lẹ́yìn náà, ó lọ títí dé Asimoni, ó tọ ipa odò Ijipti, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Òun ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ Juda ní apá ìhà gúsù.


Ààlà àwọn ará Amori bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ̀ òkè Akirabimu, láti Sela lọ sókè.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan