Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 15:2 - Yoruba Bible

2 Ààlà ilẹ̀ wọn, ní ìhà gúsù lọ láti òpin Òkun Iyọ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ati àla gusù wọn ni lati eti Okun Iyọ̀ lọ, lati ibi kọ̀rọ omi nì lọ ti o dojukọ ìha gusù:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ààlà wọn ní ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti etí òpin ìhà gúúsù Òkun Iyọ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 15:2
8 Iomraidhean Croise  

Gbogbo wọn pa àwọn ọmọ ogun wọn pọ̀ ní àfonífojì Sidimu (tí ó tún ń jẹ́ òkun iyọ̀).


OLUWA yóo pa Ijipti run patapata. Yóo na ọwọ́ ìjì líle sí orí odò Pirati, yóo sì pín in sí ọ̀nà meje, kí àwọn eniyan lè máa ríbi là á kọjá.


“Ní apá ìhà ìlà oòrùn, ààlà náà yóo lọ láti Hasari Enọni tí ó wà láàrin Haurani ati Damasku, ní ẹ̀gbẹ́ odò Jọdani tí ó wà láàrin Gileadi ati ilẹ̀ Israẹli, títí dé òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì lọ títí dé Tamari. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìlà oòrùn.


Ó ní, “Omi yìí ń ṣàn lọ sí Araba, ní ìhà ìlà oòrùn, nígbà tí ó bá sì ṣàn wọ inú òkun, omi inú òkun, yóo di omi tí ó mọ́ gaara.


Ilẹ̀ yín ní ìhà gúsù yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Sini lẹ́bàá ààlà Edomu. Ààlà yín ní ìhà gúsù yóo jẹ́ láti òpin Òkun-Iyọ̀ ní ìlà oòrùn.


Àpèjúwe ìpín tí ó kan ẹ̀yà Juda lára ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà, tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn nìyí: Ilẹ̀ náà lọ títí dé apá ìhà gúsù, ní ààlà ilẹ̀ Edomu, títí dé aṣálẹ̀ Sini.


láti apá etí òkun tí ó kọjú sí ìhà gúsù lọ títí dé àtigun òkè Akirabimu. Ó lọ títí dé Sini, ó tún lọ sí apá gúsù Kadeṣi Banea. Ó kọjá lọ lẹ́bàá Hesironi títí dé Adari, kí ó tó wá yípo lọ sí ìhà Kaka.


omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá ní òkèèrè ní ìlú Adamu tí ó wà lẹ́bàá Saretani. Èyí tí ó ń ṣàn lọ sí Òkun Araba tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀ gé kúrò, ó sì dá dúró. Àwọn eniyan náà rékọjá sí òdìkejì ìlú Jẹriko.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan