Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 15:1 - Yoruba Bible

1 Àpèjúwe ìpín tí ó kan ẹ̀yà Juda lára ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà, tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn nìyí: Ilẹ̀ náà lọ títí dé apá ìhà gúsù, ní ààlà ilẹ̀ Edomu, títí dé aṣálẹ̀ Sini.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 ILẸ ẹ̀ya awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn si dé àgbegbe Edomu, ni aginjù Sini, ni ìha gusù, ni apa ipẹkun gusù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ìpín fún ẹ̀yà Juda, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbègbè Edomu, títí dé aginjù Sini ní òpin ìhà gúúsù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 15:1
13 Iomraidhean Croise  

Àwọn ọmọ Jakọbu jẹ́ mejila. Àwọn tí Lea bí ni: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu. Lẹ́hìn rẹ̀ ni ó bí Simeoni, Lefi, Juda, Isakari ati Sebuluni.


Solomoni ati àwọn ọmọ Israẹli ṣe Àjọ̀dún Àgọ́ Àjọ níbẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan láti Ẹnu Ọ̀nà Hamati títí dé odò kékeré Ijipti ni wọ́n péjọ níwájú OLUWA fún ọjọ́ meje.


“Ní ìhà gúsù, ilẹ̀ yín yóo lọ láti Tamari dé àwọn odò Meriba Kadeṣi, títí yóo fi kan odò Ijipti títí lọ dé Òkun-ńlá. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìhà gúsù.


Ìpín ti Juda yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Reubẹni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.


Nígbà tí a ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́ adura wa, ó sì rán angẹli rẹ̀ láti mú wa jáde kúrò ní Ijipti. Nisinsinyii a ti dé Kadeṣi, ìlú kan tí ó wà lẹ́yìn odi agbègbè rẹ.


láti Idumea ati apá ìlà oòrùn odò Jọdani ati agbègbè Tire ati ti Sidoni. Ogunlọ́gọ̀ eniyan wọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó ń ṣe.


Nítorí pé, ẹ̀yin mejeeji ni ẹ kò hùwà òtítọ́ sí mi láàrin àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí ẹ wà ní odò Meriba Kadeṣi, ní aṣálẹ̀ Sini. Ẹ tàbùkù mi lójú gbogbo àwọn eniyan, ẹ kò bọ̀wọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ níwájú àwọn eniyan náà.


Gègé ni wọ́n ṣẹ́, tí wọ́n fi pín in fún ẹ̀yà mẹsan-an ati ààbọ̀ ninu ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.


Ààlà ilẹ̀ wọn, ní ìhà gúsù lọ láti òpin Òkun Iyọ̀,


Ọ̀nà meje ni wọn yóo pín ilẹ̀ náà sí, àwọn ẹ̀yà Juda kò ní kúrò ní àyè tiwọn ní apá ìhà gúsù, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀yà Josẹfu tí wọ́n wà ní agbègbè tiwọn ní apá ìhà àríwá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan