Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 13:9 - Yoruba Bible

9 láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba títí dé Diboni;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji na, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ Medeba titi dé Diboni;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ó sì lọ títí láti Aroeri tí ń bẹ létí Àfonífojì Arnoni, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárín Àfonífojì náà, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Medeba títí dé Diboni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 13:9
15 Iomraidhean Croise  

Wọ́n ré odò Jọdani kọjá, wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù Aroeri, ìlú tí ó wà ní ààrin àfonífojì, ní agbègbè Gadi. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti lọ sí ìhà àríwá, títí dé Jaseri.


Wọ́n yá ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ọba Maaka pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n wá, wọ́n sì pàgọ́ ogun wọn sí ẹ̀bá Medeba. Àwọn ará Amoni náà wá kó àwọn ọmọ ogun wọn jọ láti gbogbo ìlú wọn.


Ọ̀rọ̀ lórí àwọn ìletò ati àwọn pápá oko wọn, àwọn ará Juda kan ń gbé Kiriati Ariba ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, àwọn mìíràn sì ń gbé Diboni ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, ati ní Jekabuseeli ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀,


Àwọn ọmọbinrin Diboni ti gun àwọn ibi pẹpẹ tí wọ́n ti ń bọ̀rìṣà lọ, wọ́n lọ sọkún. Moabu ń pohùnréré ẹkún nítorí Nebo ati Medeba. Gbogbo orí wọn pá, wọ́n sì ti fá gbogbo irùngbọ̀n wọn.


Sọ̀kalẹ̀ kúrò ninu ògo rẹ, kí o jókòó lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, ìwọ tí ò ń gbé Diboni! Nítorí pé ẹni tí óo pa Moabu run ti dojú kọ ọ́, ó sì ti wó àwọn ibi ààbò rẹ̀.


Diboni, Nebo, ati Beti Dibilataimu,


Apanirun yóo wọ gbogbo ìlú, ìlú kankan kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀; àwọn àfonífojì yóo pòórá, a óo sì pa àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.


Ṣugbọn nisinsinyii, a ti pa ìrandíran wọn run, láti Heṣiboni dé Diboni, láti Naṣimu dé Nofa lẹ́bàá Medeba.”


Láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni lọ, ati ìlú ńlá tí ó wà ní àfonífojì, títí dé Gileadi, kò sí ìlú tí ó ju agbára wa lọ. OLUWA Ọlọrun wa fi gbogbo wọn lé wa lọ́wọ́,


“Nígbà tí a gba ilẹ̀ náà nígbà náà, àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo fún, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni ati ìdajì agbègbè olókè ti Gileadi, pẹlu gbogbo àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀.


Àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo sì fún ní agbègbè Gileadi títí dé àfonífojì Anoni, ààrin gbùngbùn àfonífojì náà ni ààlà ilẹ̀ wọn, títí lọ kan odò Jaboku, tíí ṣe ààlà àwọn ará Amoni;


Wọ́n ṣẹgun Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé ìlú Heṣiboni. Ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri, tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati láti agbede meji àfonífojì náà, títí dé odò Jaboku, tí í ṣe ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amoni, ó jẹ́ ìdajì ilẹ̀ Gileadi;


ati gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, tí ó jọba ní Heṣiboni, títí kan ààlà àwọn ará Amoni;


Ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati gbogbo ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba.


Ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase gba ilẹ̀ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan