Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 13:7 - Yoruba Bible

7 Ẹ pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an yòókù ati ìdajì ẹ̀yà Manase.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Njẹ nitorina pín ilẹ yi ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya mẹsan, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 pín ilẹ̀ yìí ní ilẹ̀ ìní fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn-án àti ìdajì ẹ̀yà Manase.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 13:7
12 Iomraidhean Croise  

Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n sì jogún èrè iṣẹ́ àwọn eniyan náà.


Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde kí wọn ó tó dé ibẹ̀; ó pín ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn bí ohun ìní; ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli jókòó ninu àgọ́ wọn.


“Nígbà tí ẹ bá pín ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan, ẹ ya ilẹ̀ kan sọ́tọ̀ fún OLUWA, tí yóo jẹ́ ilẹ̀ mímọ́. Gígùn rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ. Ilẹ̀ mímọ́ ni gbogbo ilẹ̀ náà yóo jẹ́.


Gègé ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà Israẹli. Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ, sì fún àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kékeré. Ilẹ̀ tí gègé olukuluku bá mú ni yóo jẹ́ tirẹ̀, láàrin àwọn ẹ̀yà yín ni ẹ óo ti pín ilẹ̀ náà.


Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ óo fi gègé pín. Ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an ààbọ̀ yòókù.


Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, láti Lẹbanoni, títí dé Misirefoti Maimu, ati gbogbo àwọn ará Sidoni ni n óo lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn, ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, bí mo ti pàṣẹ fun yín.


Ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase gba ilẹ̀ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani;


Gègé ni wọ́n ṣẹ́, tí wọ́n fi pín in fún ẹ̀yà mẹsan-an ati ààbọ̀ ninu ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan