Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 13:5 - Yoruba Bible

5 ati ilẹ̀ àwọn ará Gebali, gbogbo Lẹbanoni ní apá ìlà oòrùn, láti Baaligadi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni títí dé ibodè Hamati.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ati ilẹ awọn Gebali, ati gbogbo Lebanoni ni ìha ìla-õrùn, lati Baali-gadi nisalẹ òke Hermoni titi o fi dé atiwọ̀ Hamati:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Àti ilẹ̀ àwọn ará Gebali; àti gbogbo àwọn Lebanoni dé ìlà-oòrùn, láti Baali-Gadi ní ìsàlẹ̀ Òkè Hermoni dé Lebo-Hamati.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 13:5
14 Iomraidhean Croise  

Àwọn òṣìṣẹ́ Solomoni ati ti Hiramu, ati àwọn ọkunrin mìíràn láti ìlú Gebali ni wọ́n gbẹ́ òkúta, tí wọ́n sì la igi fún kíkọ́ ilé OLUWA.


Solomoni ati àwọn ọmọ Israẹli ṣe Àjọ̀dún Àgọ́ Àjọ níbẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan láti Ẹnu Ọ̀nà Hamati títí dé odò kékeré Ijipti ni wọ́n péjọ níwájú OLUWA fún ọjọ́ meje.


àwọn ará Gebali, àwọn ọmọ Amoni, ati àwọn ọmọ Amaleki, àwọn ará Filistia ati àwọn tí ń gbé Tire.


Ṣebí bíi Kakemiṣi ni Kalino rí, tí Hamati rí bíi Aripadi, tí Samaria kò sì yàtọ̀ sí Damasku?


Ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Kalidea tẹ Sedekaya ọba, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babiloni sì ṣe ìdájọ́ fún un.


Àwọn àgbààgbà Gebali ati àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n oníṣẹ́ ọwọ́ wà lọ́dọ̀ rẹ, àwọn ni wọ́n ń fi ọ̀dà dí ọkọ̀ rẹ kí omi má baà wọnú rẹ̀. Gbogbo ọkọ̀ ojú omi ati àwọn tí ń tù wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, wọ́n ń bá ọ ra ọjà.


Ẹ lọ wo ìlú Kane; ẹ ti ibẹ̀ lọ sí Hamati, ìlú ńlá nì, lẹ́yìn náà ẹ lọ sí ìlú Gati, ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ṣé wọ́n sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yín lọ ni? Tabi agbègbè wọn tóbi ju tiyín lọ?


Àwọn eniyan náà lọ, wọ́n sì wo ilẹ̀ náà láti aṣálẹ̀ Sini títí dé Rehobu ati ni ẹ̀bá ibodè Hamati.


Láti ibẹ̀ lọ dé ẹnu ibodè Hamati, títí dé Sedadi,


Ó ní kí á dìde, kí á bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí agbègbè olókè ti àwọn ará Amori, ati gbogbo agbègbè tí ó yí wọn ká ní Araba, ní àwọn agbègbè olókè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, ati èyí tí ó wà létí òkun tí wọn ń pè ní Mẹditarenia, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Lẹbanoni, títí dé odò ńlá nnì, àní odò Yufurate.


Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí n kọjá sí òdìkejì Jọdani kí n sì rí ilẹ̀ dáradára náà, agbègbè olókè dáradára nnì ati Lẹbanoni.’


Láti òkè Halaki títí lọ sí Seiri, títí dé Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni. Ó mú gbogbo àwọn ọba wọn, ó pa wọ́n.


Ó ranṣẹ sí àwọn ará Kenaani ní ìhà ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Jebusi ní àwọn agbègbè olókè, ati àwọn ará Hifi tí wọ́n wà ní abẹ́ òkè Herimoni ní ilẹ̀ Misipa.


Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, láti Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni títí dé òkè Halaki, ní apá Seiri. Joṣua pín ilẹ̀ wọn fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan