Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 13:4 - Yoruba Bible

4 Lẹ́yìn náà, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Meara, tíí ṣe ilẹ̀ àwọn ará Sidoni, títí dé Afeki ní ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amori,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Gbogbo ilẹ awọn ara Kenaani, ati Meara ti awọn ara Sidoni, dé Afeki, titi dé àgbegbe awọn Amori:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 láti gúúsù; gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, láti Arah ti àwọn ará Sidoni títí ó fi dé Afeki, agbègbè àwọn ará Amori;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 13:4
11 Iomraidhean Croise  

Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òjò, ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó sì kó wọn lọ sí ìlú Afeki, láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.


Àwọn ọmọ ogun Siria yòókù sì sá lọ sí ìlú Afeki; odi ìlú náà sì wó pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaarin (27,000) tí ó kù ninu wọn. Benhadadi pàápàá sá wọ inú ìlú lọ, ó sì sá pamọ́ sinu yàrá ní ilé kan.


kí o sì sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Jerusalẹmu pé: “Ilẹ̀ Kenaani ni a bí ọ sí; ibẹ̀ ni orísun rẹ. Ará Amori ni baba rẹ ará Hiti sì ni ìyá rẹ.


Èmi fúnra mi ni mo mu yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, mo mu yín la aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún, kí ẹ lè gba ilẹ̀ àwọn ará Amori.


Joṣua ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ náà, ati àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Nẹgẹbu ní apá gúsù, ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ati gbogbo àwọn ọba wọn. Kò dá ẹnikẹ́ni sí, gbogbo wọn patapata ni ó parun gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli pa fún un.


Ó ranṣẹ sí àwọn ará Kenaani ní ìhà ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Jebusi ní àwọn agbègbè olókè, ati àwọn ará Hifi tí wọ́n wà ní abẹ́ òkè Herimoni ní ilẹ̀ Misipa.


Uma, Afeki, ati Rehobu wà, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejilelogun.


Ní àkókò náà, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọmọ Israẹli náà bá kó ogun jáde láti bá wọn jà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pàgọ́ sí Ebeneseri, àwọn ọmọ ogun Filistini sì pa tiwọn sí Afeki.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan