Joṣua 13:3 - Yoruba Bible3 láti odò Ṣihori, ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Ijipti, títí lọ sí apá àríwá ní ààlà Ekironi tí ó jẹ́ ti àwọn ará Kenaani, (Marun-un ni ọba àwọn ará Filistia, àwọn nìwọ̀nyí: ọba Gasa, ti Aṣidodu, ti Aṣikeloni, ti Gati, ati ti Ekironi) ati ilẹ̀ àwọn Afimu ní ìhà gúsù. Faic an caibideilBibeli Mimọ3 Lati Ṣihori, ti mbẹ niwaju Egipti, ani titi dé àgbegbe Ekroni ni ìha ariwa, ti a kà kún awọn ara Kenaani: awọn ijoye Filistia marun; awọn ara Gasa, ati awọn ara Aṣdodi, awọn ara Aṣkeloni, awọn Gitti, ati awọn ara Ekroni; awọn Affimu pẹlu ni gusù: Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní3 láti odò Ṣihori ní ìlà-oòrùn Ejibiti sí agbègbè Ekroni ìhà àríwá, gbogbo rẹ̀ ni a kà kún Kenaani (agbègbè ìjòyè Filistini márùn-ún ní Gasa, Aṣdodu, Aṣkeloni, Gitti àti Ekroni; ti àwọn ará Affimu); Faic an caibideil |
Àwọn eniyan náà bi wọ́n pé, “Kí ni kí á fi ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù?” Àwọn babalóòṣà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún marun-un, ati ti èkúté marun-un, kí ẹ fi ranṣẹ. Kókó ọlọ́yún wúrà marun-un ati èkúté marun-un dúró fún àwọn ọba Filistini maraarun. Nítorí àjàkálẹ̀ àrùn kan náà ni ó kọlu gbogbo yín ati àwọn ọba yín maraarun.