Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 13:1 - Yoruba Bible

1 Ní àkókò yìí, Joṣua ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí i. OLUWA bá sọ fún un pé, “Ogbó ti dé sí ọ, ṣugbọn ilẹ̀ pupọ ni ó kù láti gbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 JOṢUA si gbó o si pọ̀ li ọjọ́; OLUWA si wi fun u pe, Iwọ gbó, iwọ si pọ̀ li ọjọ́, ilẹ pipọ̀pipọ si kù lati gbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà tí Joṣua sì darúgbó tí ọjọ́ orí rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ, Olúwa sọ fún un pé, “Ìwọ ti darúgbó púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ sì kù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún yín láti gbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 13:1
12 Iomraidhean Croise  

Abrahamu ati Sara ti di àgbàlagbà ní àkókò yìí, ogbó ti dé sí wọn, ọjọ́ ti pẹ́ tí Sara ti rí nǹkan oṣù rẹ̀ kẹ́yìn.


Ní àkókò yìí, Dafidi ọba ti di arúgbó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣọ tí ó nípọn ni wọ́n fi ń bò ó, òtútù a tún máa mú un.


Láti ibẹ̀ lọ sí ìhà gúsù lẹ́bàá odò Jọdani, yóo parí sí Òkun-Iyọ̀. Àwọn ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín.”


“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fun yín, gbogbo ilẹ̀ náà ni yóo jẹ́ tiyín. Àwọn ààlà ilẹ̀ yín nìwọ̀nyí.’


Ṣugbọn wọn kò ní ọmọ, nítorí pé Elisabẹti yàgàn. Àwọn mejeeji ni wọ́n sì ti di arúgbó.


OLUWA Ọlọrun yín tìkalára rẹ̀ ni yóo ṣiwaju yín lọ, yóo ba yín pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà run, tí ẹ ó fi lè gba ilẹ̀ wọn. Joṣua ni yóo sì jẹ́ olórí, tí yóo máa ṣiwaju yín lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí.


Ilẹ̀ tí ó kù nìwọ̀nyí: gbogbo agbègbè àwọn ará Filistia ati ti Geṣuri;


OLUWA ti dá ẹ̀mí mi sí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, láti nǹkan bí ọdún marunlelogoji tí OLUWA ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mose nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń rìn ninu aṣálẹ̀. Nisinsinyii, mo ti di ẹni ọdún marundinlaadọrun,


Joṣua bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ìgbà wo ni ẹ fẹ́ dúró dà kí ẹ tó lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fun yín.


Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún Joṣua pé,


Lẹ́yìn náà, nígbà tó yá, Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan