Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 12:1 - Yoruba Bible

1 Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, wọ́n sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani, láti àfonífojì Arinoni títí dé òkè Herimoni, pẹlu gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NJẸ wọnyi ni awọn ọba ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli pa, ti nwọn si gbà ilẹ wọn li apa keji Jordani, ni ìha ìla-õrùn, lati odò Arnoni lọ titi dé òke Hermoni, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ni ìha ìla-õrun:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé Òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 12:1
24 Iomraidhean Croise  

Geberi, ọmọ Uri, ni alákòóso agbègbè Gileadi, níbi tí Sihoni ọba àwọn ará Amori ati Ogu ọba Baṣani ti jọba tẹ́lẹ̀ rí. Lẹ́yìn àwọn alákòóso mejeejila wọnyi, alákòóso àgbà kan tún wà fún gbogbo ilẹ̀ Juda.


Ó dàbí ìrì òkè Herimoni, tí ó sẹ̀ sórí òkè Sioni. Níbẹ̀ ni OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun, àní, ìyè ainipẹkun.


Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;


Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù, òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.


Àwọn ọmọbinrin Moabu dúró létí odò Anoni, wọ́n ń rìn síwá, sẹ́yìn, wọ́n ń lọ sókè, sódò, bí ọmọ ẹyẹ tí a lé kúrò ninu ìtẹ́.


Wọ́n tún ṣí kúrò ní àfonífojì Seredi, wọ́n pa àgọ́ wọn sí òdìkejì odò Arinoni, tí ó wà ní aṣálẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti agbègbè àwọn ará Amori. Odò Arinoni jẹ́ ààlà ilẹ̀ Moabu, ó wà láàrin ilẹ̀ Moabu ati ilẹ̀ Amori.


Àwọn ọmọ Israẹli bá ranṣẹ sí Sihoni ọba àwọn ará Amori pé,


Àwọn ọmọ Israẹli pa pupọ ninu wọn, wọ́n gba ilẹ̀ wọn láti odò Arinoni lọ dé odò Jaboku títí dé ààlà àwọn ará Amoni. Wọn kò gba ilẹ̀ àwọn ará Amoni nítorí pé wọ́n jẹ́ alágbára.


A kò ní bá wọn pín ninu ilẹ̀ òdìkejì odò Jọdani nítorí pé a ti ní ilẹ̀ ìní tiwa ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani níhìn-ín.”


Nípa àṣẹ rẹ̀ ni a óo ré odò Jọdani kọjá, a óo lọ jagun ní ilẹ̀ Kenaani, kí ilẹ̀ ìhà ìlà oòrùn Jọdani lè jẹ́ tiwa.”


Mose bá fi ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori, ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani ati àwọn ilẹ̀ ati àwọn ìlú tí ó yí wọn ká fún àwọn ọmọ Gadi, àwọn ọmọ Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu.


“Ẹ dìde, ẹ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò yín, kí ẹ sì ré àfonífojì Anoni kọjá. Mo ti fi Sihoni, ọba Heṣiboni, ní ilẹ̀ àwọn ará Amori, le yín lọ́wọ́, àtòun ati ilẹ̀ rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí bá a jagun, kí ẹ sì máa gba ilẹ̀ rẹ̀.


Sihoni bá jáde sí wa, òun ati àwọn eniyan rẹ̀, láti bá wa jagun ní Jahasi.


“Lẹ́yìn náà, a gbéra, a doríkọ ọ̀nà Baṣani. Ogu, ọba Baṣani, ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ṣígun wá pàdé wa ní Edirei.


Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní àwọn òfin;


nígbà tí wọ́n dé òdìkejì odò Jọdani, ní àfonífojì tí ó dojú kọ Betipeori, ní ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni. Mose ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun Sihoni nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti.


láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni títí dé òkè Sirioni (tí à ń pè ní òkè Herimoni),


títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti fun yín, tí wọn yóo sì fi gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fún wọn. Nígbà náà ni ẹ óo tó pada sí orí ilẹ̀ yín, tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fun yín ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, ẹ óo sì máa gbé ibẹ̀.”


Láti òkè Halaki títí lọ sí Seiri, títí dé Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni. Ó mú gbogbo àwọn ọba wọn, ó pa wọ́n.


Ó ranṣẹ sí àwọn ará Kenaani ní ìhà ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Jebusi ní àwọn agbègbè olókè, ati àwọn ará Hifi tí wọ́n wà ní abẹ́ òkè Herimoni ní ilẹ̀ Misipa.


Ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase gba ilẹ̀ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani;


Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun yín ti fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn; nítorí náà, ẹ pada lọ sí ilẹ̀ yín, níbi tí ohun ìní yín wà, àní ilẹ̀ tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín ní òdìkejì odò Jọdani.


Wọ́n bá gba aṣálẹ̀, wọ́n sì yípo lọ sí òdìkejì ilẹ̀ àwọn ará Edomu ati ti àwọn ará Moabu, títí tí wọ́n fi dé apá ìlà oòrùn ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Wọ́n pàgọ́ wọn sí òdìkejì ilẹ̀ Anoni. Ṣugbọn wọn kò wọ inú ilẹ̀ àwọn ará Moabu, nítorí pé, ààlà ilẹ̀ Moabu ni Anoni wà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan