Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:8 - Yoruba Bible

8 OLUWA fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n. Wọ́n lé wọn títí dé Sidoni ati Misirefoti Maimu, ati apá ìlà oòrùn títí dé àfonífojì Misipa, wọ́n pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 OLUWA si fi wọn lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn, nwọn si lé wọn titi dé Sidoni nla ati titi dé Misrefoti-maimu, ati dé afonifoji Mispa ni ìha ìla-õrùn; nwọn si pa wọn tobẹ̃ ti kò kù ẹnikan silẹ fun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Olúwa sì fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́. Wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì lépa wọn ní gbogbo ọ̀nà títí dé Sidoni ńlá, sí Misrefoti-Maimu, àti sí Àfonífojì Mispa ní ìlà-oòrùn, títí tí kò fi ku ẹnìkankan sílẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:8
13 Iomraidhean Croise  

Àkọ́bí Kenaani ni Sidoni, òun náà ni ó bí Heti.


“Sebuluni yóo máa gbé etí òkun, ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ kò ní níye, Sidoni ni yóo jẹ́ ààlà rẹ̀.


Wọ́n lọ sí Gileadi, ati sí Kadeṣi ní ilẹ̀ àwọn ará Hiti. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí Dani. Láti Dani, wọ́n lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé Sidoni.


Ojú tì ọ́, ìwọ Sidoni nítorí òkun ti fọhùn, agbami òkun ti sọ̀rọ̀, ó ní: “N kò rọbí, bẹ́ẹ̀ ni n kò bímọ; n kò tọ́ àwọn ọmọ dàgbà rí kì báà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.”


Tirẹ̀ ni ilẹ̀ Hamati tí ó bá Israẹli pààlà. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìlú Tire ati Sidoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.


nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi wọ́n le yín lọ́wọ́, tí ẹ bá sì ṣẹgun wọn, píparun ni ẹ gbọdọ̀ pa wọ́n run. Ẹ kò gbọdọ̀ bá wọn dá majẹmu, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú fún wọn rárá.


Nítorí náà, kí ẹ mọ̀ lónìí pé, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń lọ níwájú yín, bíi iná ajónirun. Yóo pa wọ́n run, yóo sì tẹ orí wọn ba fun yín, nítorí náà, kíá ni ẹ óo lé wọn jáde, tí ẹ óo sì pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.


Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ti pa wọ́n ní ìpakúpa tán, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ pa gbogbo wọn run, tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù sì ti sá wọ àwọn ìlú olódi wọn lọ tán,


Ó ranṣẹ sí àwọn ará Kenaani ní ìhà ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Jebusi ní àwọn agbègbè olókè, ati àwọn ará Hifi tí wọ́n wà ní abẹ́ òkè Herimoni ní ilẹ̀ Misipa.


Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá jálù wọ́n lójijì ní etí odò Meromu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn jagun.


Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, láti Lẹbanoni, títí dé Misirefoti Maimu, ati gbogbo àwọn ará Sidoni ni n óo lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn, ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, bí mo ti pàṣẹ fun yín.


Eburoni, Rehobu, Hamoni, ati Kana, títí dé Sidoni Ńlá;


OLUWA fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo àyíká wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Kò sì sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè ṣẹgun wọn, nítorí pé OLUWA ti fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan