Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:6 - Yoruba Bible

6 OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí pé ní ìwòyí ọ̀la, òkú wọn ni n óo fi lé Israẹli lọ́wọ́. Dídá ni kí ẹ dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, kí ẹ sì sun gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru nitori wọn: nitori li ọla li akokò yi emi o fi gbogbo wọn tọrẹ niwaju Israeli ni pipa: iwọ o já patì ẹṣin wọn, iwọ o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí ní àkókò yìí ní ọ̀la, gbogbo wọn ni èmi yóò fi lé Israẹli lọ́wọ́ ní pípa. Ìwọ yóò já iṣan ẹ̀yìn ẹṣin wọn, ìwọ yóò sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:6
24 Iomraidhean Croise  

Ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ẹlẹ́ṣin ni Dafidi gbà lọ́wọ́ rẹ̀, ati ọ̀kẹ́ kan àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ rìn. Dafidi dá ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ṣugbọn ó dá ọgọrun-un (100) sí ninu wọn.


Eliṣa dáhùn pé, “Má bẹ̀rù nítorí pé àwọn tí wọ́n wà pẹlu wa ju àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn lọ.”


Ní ọ̀la, ẹ kógun lọ bá wọn; wọn yóo gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Sisi wá, ẹ óo rí wọn ní òpin àfonífojì ní apá ìlà oòrùn aṣálẹ̀ Jerueli.


“Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọrun. A gbé mi ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, a gbé mi ga ní ayé.”


OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa, Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa.


Ó dáwọ́ ogun dúró ní gbogbo ayé, ó ṣẹ́ ọrun, ó rún ọ̀kọ̀, ó dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun.


Olódodo a máa rìn ní ọ̀nà òtítọ́, ibukun ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n tẹ̀lé e.


Ẹ sọ pé ó tì o, ẹ̀yin óo gun ẹṣin sálọ ni. Nítorí náà sísá ni ẹ óo sálọ. Ẹ sọ pé ẹṣin tí ó lè sáré ni ẹ óo gùn. Nítorí náà àwọn tí yóo máa le yín, wọn óo lè sáré gan-an ni.


Àwọn tí ó ń lọ sí Ijipti fún ìrànlọ́wọ́ gbé! Àwọn tí wọ́n gbójú lé ẹṣin; tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun nítorí pé wọ́n pọ̀, tí wọ́n gbójú lé ẹṣin nítorí pé wọ́n lágbára! Wọn kò gbójú lé Ẹni Mímọ́ Israẹli, wọn kò sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA.


Àwọn ará ìlú Israẹli yóo tú síta, wọn yóo dáná sun àwọn ohun ìjà ogun: apata ati asà, ọrun ati ọfà, àáké ati ọ̀kọ̀. Ọdún meje ni wọn yóo fi dáná sun wọ́n.


Asiria kò lè gbà wá là, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gun ẹṣin; a kò sì ní pe oriṣa, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wa, ní Ọlọrun wa mọ́. OLUWA, ìwọ ni ò ń ṣàánú fún ọmọ tí kò lẹ́nìkan.”


OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Mo ti dójú lé ọ. N óo dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, n óo sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun rẹ. Gbogbo ohun tí o ti gbà lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn ni n óo gbà pada lọ́wọ́ rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn àwọn iranṣẹ rẹ mọ́.”


Píparun ni ẹ óo pa gbogbo àwọn eniyan tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi lé yín lọ́wọ́ run, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọdọ̀ bọ àwọn oriṣa wọn, nítorí ohun ìkọsẹ̀ ni wọn yóo jẹ́ fun yín.


OLUWA wí fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù wọn, nítorí pé mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní lè ṣẹgun rẹ.”


Gbogbo àwọn ọba wọnyi parapọ̀, wọ́n kó gbogbo ọmọ ogun wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n sì pàgọ́ sí etí odò Meromu.


Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá jálù wọ́n lójijì ní etí odò Meromu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn jagun.


Joṣua ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ pé kí ó ṣe sí wọn: ó dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, ó sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn níná.


Joṣua sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nítorí pé OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrin yín ní ọ̀la.”


Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni ló ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli tún bèèrè pé, “Ṣé kí á tún lọ gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tíí ṣe arakunrin wa àbí kí á dáwọ́ dúró?” OLUWA dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ lọ gbógun tì wọ́n, nítorí pé, lọ́la ni n óo fi wọ́n le yín lọ́wọ́.”


OLUWA sọ fún un ní òru ọjọ́ kan náà pé, “Gbéra, lọ gbógun ti àgọ́ náà, nítorí pé mo ti fi lé ọ lọ́wọ́.


Wọ́n sọ fún àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wá láti Jabeṣi-Gileadi pé, “Ẹ sọ fún àwọn eniyan yín pé, ní ọ̀sán ọ̀la, a óo gbà wọ́n kalẹ̀.” Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi gbọ́ ìròyìn náà, inú wọn dùn gidigidi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan