Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:5 - Yoruba Bible

5 Gbogbo àwọn ọba wọnyi parapọ̀, wọ́n kó gbogbo ọmọ ogun wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n sì pàgọ́ sí etí odò Meromu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Gbogbo awọn ọba wọnyi si pejọ pọ̀, nwọn wá nwọn si dó ṣọkan ni ibi omi Meromu, lati fi ijà fun Israeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Gbogbo àwọn ọba yìí pa ọmọ-ogun wọn pọ̀, wọ́n sì pa ibùdó sí ibi omi Meromu láti bá Israẹli jà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:5
9 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí àwọn ará Siria rí i pé, àwọn ọmọ ogun Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ.


OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ! Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi!


Nígbà tí wọ́n fojú kàn án, ẹnu yà wọ́n, ìpayà mú wọn, wọ́n sì sá;


Ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ kó ara yín jọ! A óo fọ yín túútúú. Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè. Ẹ di ara yín ní àmùrè; a óo fọ yín túútúú. Ẹ di ara yín ní àmùrè, a óo fọ yín túútúú.


Gbogbo wọn jáde pẹlu gbogbo ọmọ ogun wọn, wọ́n pọ̀ yanturu bí eṣú. Wọ́n dàbí iyanrìn etí òkun. Ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò lóǹkà.


OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí pé ní ìwòyí ọ̀la, òkú wọn ni n óo fi lé Israẹli lọ́wọ́. Dídá ni kí ẹ dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, kí ẹ sì sun gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”


gbogbo wọn parapọ̀, wọ́n fi ohùn ṣọ̀kan láti bá Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli jagun.


Ẹ̀mí Èṣù ni àwọn ẹ̀mí náà, wọ́n sì lè ṣe ohun abàmì. Wọ́n jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, láti kó wọn jọ fún ogun ní ọjọ́ ńlá ti Ọlọrun alágbára jùlọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan