Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:4 - Yoruba Bible

4 Gbogbo wọn jáde pẹlu gbogbo ọmọ ogun wọn, wọ́n pọ̀ yanturu bí eṣú. Wọ́n dàbí iyanrìn etí òkun. Ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò lóǹkà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Nwọn si jade, awọn ati gbogbo ogun wọn pẹlu wọn, ọ̀pọlọpọ enia, bi yanrin ti mbẹ li eti okun fun ọ̀pọ, ati ẹṣin ati kẹkẹ́ pipọ̀pipọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Wọ́n sì jáde pẹ̀lú gbogbo ogun wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun ńlá, wọ́n sì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí Òkun

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:4
8 Iomraidhean Croise  

n óo bukun ọ lọpọlọpọ, n óo sọ àwọn ọmọ ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi yanrìn etí òkun. Àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóo máa ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo ìgbà.


Ìwọ ni o ṣá sọ fún mi pé, ‘Ire ni n óo ṣe fún ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí iyanrìn etí òkun tí ẹnikẹ́ni kò ní lè kà tán.’ ”


Ìmọ̀ràn tèmi ni pé kí o kó gbogbo àwọn ọmọ ogun jọ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí wọ́n pọ̀ bíi yanrìn etí òkun. Ìwọ gan-an ni kí o ṣáájú wọn lọ sí ogun náà.


Àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ bíi yanrìn inú òkun, wọ́n ń rí jẹ, wọ́n ń rí mu, wọ́n sì láyọ̀.


Àwọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú, ṣugbọn àwa óo dìde, a óo sì dúró ṣinṣin.


Gbogbo àwọn ọba wọnyi parapọ̀, wọ́n kó gbogbo ọmọ ogun wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n sì pàgọ́ sí etí odò Meromu.


Àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati ti Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìlà oòrùn pọ̀ nílẹ̀ lọ bí eṣú àwọn ràkúnmí wọn kò níye, wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun.


Àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n ní ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ẹgbaata (6,000) ẹlẹ́ṣin, àwọn ọmọ ogun wọn sì pọ̀ bí eṣú. Wọ́n lọ sí Mikimaṣi ní ìhà ìlà oòrùn Betafeni, wọ́n pàgọ́ wọn sibẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan