Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:3 - Yoruba Bible

3 Ó ranṣẹ sí àwọn ará Kenaani ní ìhà ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Jebusi ní àwọn agbègbè olókè, ati àwọn ará Hifi tí wọ́n wà ní abẹ́ òkè Herimoni ní ilẹ̀ Misipa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ati si awọn ara Kenaani ni ìha ìla-õrùn ati ni ìha ìwọ-õrùn, ati awọn Amori, ati si awọn Hitti, ati si awọn Perissi, ati si awọn Jebusi lori òke, ati si awọn Hifi nisalẹ Hermoni ni ilẹ Mispa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 sí àwọn ará Kenaani ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn; sí àwọn Amori, Hiti, Peresi àti Jebusi ní orí òkè; àti sí àwọn Hifi ní ìsàlẹ̀ Hermoni ní agbègbè Mispa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:3
30 Iomraidhean Croise  

Ó sì sọ ọ̀wọ̀n náà ní Misipa, nítorí ó wí pé, “Kí OLUWA ṣọ́ wa nígbà tí a bá pínyà lọ́dọ̀ ara wa.


Nígbà tí angẹli OLUWA náà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti máa pa Jerusalẹmu run, OLUWA yí ọkàn pada nípa jíjẹ tí ó ń jẹ àwọn eniyan náà níyà. Ó bá wí fún angẹli náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Níbi ìpakà Arauna ará Jebusi kan ni angẹli náà wà nígbà náà.


Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí apá gúsù. Wọ́n dé ìlú olódi ti Tire, títí lọ dé gbogbo ìlú àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Kenaani. Níkẹyìn, wọ́n wá sí Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù Juda.


Asa ọba bá kéde ní gbogbo ilẹ̀ Juda, ó ní kí gbogbo eniyan patapata láìku ẹnìkan, lọ kó gbogbo òkúta ati igi ti Baaṣa fi ń mọ odi Rama kúrò ní Rama. Igi ati òkúta náà ni Asa fi mọ odi ìlú Geba tí ó wà ní ilẹ̀ Bẹnjamini, ati ti ìlú Misipa.


Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù lára àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, àwọn tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli–


Ó dàbí ìrì òkè Herimoni, tí ó sẹ̀ sórí òkè Sioni. Níbẹ̀ ni OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun, àní, ìyè ainipẹkun.


Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù, òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.


Máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni, iyawo mi, máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni. Kúrò ní ṣóńṣó òkè Amana, kúrò lórí òkè Seniri ati òkè Herimoni, kúrò ninu ihò kinniun, ati ibi tí àwọn ẹkùn ń gbé.


Ní tèmi, Misipa ni n óo máa gbé kí n lè máa rí ààyè bá àwọn ará Kalidea tí wọn wá dótì wá sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin ẹ máa kó ọtí, èso, ati òróró jọ sinu ìkòkò yín, kí ẹ sì máa gbé àwọn ìlú tí ẹ ti gbà.”


Jeremaya bá pada sọ́dọ̀ Gedalaya, ọmọ Ahikamu ní Misipa, ó sì ń gbé pẹlu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan tí wọn kù ní ilẹ̀ náà.


Ni gbogbo àwọn tí Iṣimaeli kó lẹ́rú ní Misipa bá yipada kúrò lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n lọ bá Johanani ọmọ Karea.


Iṣimaeli pa gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà pẹlu Gedalaya ní Misipa, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà níbẹ̀.


Àwọn ará Amaleki ń gbé ìhà gúsù ilẹ̀ náà. Àwọn ará Hiti, ará Jebusi ati àwọn ará Amori ń gbé àwọn agbègbè olókè. Àwọn ará Kenaani sì ń gbé lẹ́bàá òkun ati ní agbègbè Jọdani.”


láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni títí dé òkè Sirioni (tí à ń pè ní òkè Herimoni),


“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá ko yín wọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ yìí, tí ẹ bá gba ilẹ̀ náà, tí OLUWA sì lé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè jáde fun yín, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Hiti, Girigaṣi, Amori, Kenaani, Perisi, Hifi, Jebusi, àní àwọn orílẹ̀-èdè meje tí wọ́n tóbi jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ;


Láti òkè Halaki títí lọ sí Seiri, títí dé Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni. Ó mú gbogbo àwọn ọba wọn, ó pa wọ́n.


OLUWA fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n. Wọ́n lé wọn títí dé Sidoni ati Misirefoti Maimu, ati apá ìlà oòrùn títí dé àfonífojì Misipa, wọ́n pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan.


ati Gileadi ati agbègbè Geṣuri ti Maakati, ati gbogbo òkè Herimoni ati gbogbo Baṣani títí dé Saleka;


ati ilẹ̀ àwọn ará Gebali, gbogbo Lẹbanoni ní apá ìlà oòrùn, láti Baaligadi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni títí dé ibodè Hamati.


Dileani, Misipa, Jokiteeli,


Ṣugbọn àwọn eniyan Juda kò lè lé àwọn Jebusi tí wọn ń gbé inú ilẹ̀ Jerusalẹmu jáde. Àwọn Jebusi yìí sì tún wà láàrin àwọn eniyan Juda ní Jerusalẹmu títí di òní olónìí.


Èyí ni ẹ óo fi mọ̀ pé Ọlọrun alààyè wà láàrin yín, kò sì ní kùnà láti lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi, àwọn ará Perisi, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Amori, ati àwọn ará Jebusi, jáde fun yín.


Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde wá, bẹ̀rẹ̀ láti Dani ní apá ìhà àríwá títí dé Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi, ní apá ìwọ̀ oòrùn. Wọ́n kó ara wọn jọ sójú kan ṣoṣo níwájú OLUWA ní Misipa.


Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè pé, “Èwo ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli ni kò wá sí ibi àjọ níwájú OLUWA?” Nítorí pé wọ́n ti ṣe ìbúra tí ó lágbára nípa ẹni tí kò bá wá siwaju OLUWA ní Misipa, wọ́n ní, “Pípa ni a óo pa á.”


Wọ́n bá bèèrè pé, “Ẹ̀yà wo ninu Israẹli ni kò wá siwaju OLUWA ní Misipa?” Wọ́n rí i pé ẹnikẹ́ni kò wá ninu àwọn ará Jabeṣi Gileadi sí àjọ náà.


Àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA fi sílẹ̀ nìwọ̀nyí: àwọn olú-ìlú Filistini maraarun ati gbogbo ilẹ̀ Kenaani, àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Hifi tí wọn ń gbé òkè Lẹbanoni, láti òkè Baali Herimoni títí dé ẹnubodè Hamati.


Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ààrin àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi.


Samuẹli pe àwọn eniyan náà jọ siwaju OLUWA ní Misipa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan