Joṣua 11:2 - Yoruba Bible2 ati sí àwọn ọba tí wọ́n wà ní àwọn ìlú olókè ti apá ìhà àríwá, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní Araba ní ìhà gúsù Kineroti, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní Nafoti-dori ní apá ìwọ̀ oòrùn. Faic an caibideilBibeli Mimọ2 Ati si awọn ọba ti mbẹ ni ìha ariwa, lori òke, ati ti pẹtẹlẹ̀ ni ìha gusù ti Kinnerotu, ati ni ilẹ titẹju, ati ni ilẹ òke Doru ni ìha ìwọ-õrùn, Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní2 àti sí àwọn ọba ìhà àríwá tí wọ́n wà ní orí òkè ní aginjù, gúúsù ti Kinnereti, ní ẹsẹ̀ òkè ìwọ̀-oòrùn àti ní Nafoti Dori ní ìwọ̀-oòrùn; Faic an caibideil |
Joṣua ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ náà, ati àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Nẹgẹbu ní apá gúsù, ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ati gbogbo àwọn ọba wọn. Kò dá ẹnikẹ́ni sí, gbogbo wọn patapata ni ó parun gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli pa fún un.