Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:12 - Yoruba Bible

12 Joṣua gba gbogbo ìlú àwọn ọba náà, ó kó àwọn ọba wọn, ó fi idà pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí Mose iranṣẹ OLUWA ti pàṣẹ fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Ati gbogbo ilu awọn ọba wọnni, ati gbogbo ọba wọn, ni Joṣua kó, o si fi oju idà kọlù wọn, o si pa wọn run patapata, gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti palaṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Joṣua sì kó gbogbo àwọn ìlú ọba àti ọba wọn, ó sì fi idà pa wọ́n. Ó sì run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:12
18 Iomraidhean Croise  

nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi wọ́n le yín lọ́wọ́, tí ẹ bá sì ṣẹgun wọn, píparun ni ẹ gbọdọ̀ pa wọ́n run. Ẹ kò gbọdọ̀ bá wọn dá majẹmu, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú fún wọn rárá.


Nítorí náà, kí ẹ mọ̀ lónìí pé, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń lọ níwájú yín, bíi iná ajónirun. Yóo pa wọ́n run, yóo sì tẹ orí wọn ba fun yín, nítorí náà, kíá ni ẹ óo lé wọn jáde, tí ẹ óo sì pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.


Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ti pa wọ́n ní ìpakúpa tán, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ pa gbogbo wọn run, tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù sì ti sá wọ àwọn ìlú olódi wọn lọ tán,


Ní ọjọ́ náà gan-an ni Joṣua gba ìlú Makeda, ó sì fi idà pa àwọn eniyan inú rẹ̀ ati ọba wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ ni ó parun, kò dá ẹnikẹ́ni sí. Bí ó ti ṣe sí ọba Jẹriko náà ló ṣe sí ọba Makeda.


OLUWA sì fi ìlú Libina ati ọba rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́. Wọ́n fi idà pa wọ́n, wọn kò ṣẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu wọn. Bí ó ti ṣe ọba Jẹriko, náà ló ṣe sí ọba ìlú náà.


OLUWA fi ìlú Lakiṣi lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì gbà á ní ọjọ́ keji. Wọ́n fi idà pa gbogbo wọn patapata bí wọ́n ti ṣe pa àwọn ará Libina.


Wọ́n gba ìlú náà ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀ patapata gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí àwọn ará Lakiṣi.


Wọ́n gba ìlú Heburoni, wọ́n sì fi idà pa ọba ìlú náà ati gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ láìku ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí ìlú Egiloni tí wọn parun láìku ẹnìkan.


Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò sun èyíkéyìí ninu àwọn ìlú tí wọ́n kọ́ sórí òkítì níná, àfi Hasori nìkan ni Joṣua dáná sun.


Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, iranṣẹ rẹ̀, ni Mose náà ṣe pàṣẹ fún Joṣua, tí Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ohunkohun sílẹ̀ láìṣe, ninu gbogbo nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose.


Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, láti Lẹbanoni, títí dé Misirefoti Maimu, ati gbogbo àwọn ará Sidoni ni n óo lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn, ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, bí mo ti pàṣẹ fun yín.


OLUWA fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo àyíká wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Kò sì sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè ṣẹgun wọn, nítorí pé OLUWA ti fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́.


bí Mose iranṣẹ OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli ati gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ ọ́ sí inú ìwé òfin Mose pé, “Pẹpẹ tí wọ́n fi òkúta tí wọn kò gbẹ́ kọ́, tí ẹnikẹ́ni kò gbé ohun èlò irin sókè láti gbẹ́ òkúta rẹ̀.” Wọ́n rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA lórí rẹ̀.


Gbàrà tí ẹ bá ti gba ìlú náà tán, ẹ ti iná bọ̀ ọ́, kí ẹ sì ṣe bí àṣẹ OLUWA. Ó jẹ́ àṣẹ tí mo pa fun yín.”


Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Wọ́n sọ fún àwa iranṣẹ yín pé, dájúdájú, OLUWA Ọlọrun yín ti pàṣẹ fún Mose láti fun yín ní gbogbo ilẹ̀ yìí, ati láti pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀; nítorí náà ni ẹ̀rù yín ṣe bà wá. Kí ẹ má baà pa wá run ni a fi ṣe ohun tí a ṣe.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan