Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:1 - Yoruba Bible

1 Nígbà tí Jabini ọba Hasori, gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó ranṣẹ sí Jobabu, ọba Madoni, ati sí ọba Ṣimironi, ati sí ọba Akiṣafu,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O si ṣe, nigbati Jabini ọba Hasoru gbọ́ nkan wọnyi, o ranṣẹ si Jobabu ọba Madoni, ati si ọba Ṣimroni, ati si ọba Akṣafu,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà tí Jabini ọba Hasori gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó ránṣẹ́ sí Jobabu ọba Madoni, sí ọba Ṣimroni àti Akṣafu,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:1
19 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí àwọn ará Siria rí i pé, àwọn ọmọ ogun Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ.


Bẹnabinadabu, ọkọ Tafati, ọmọ Solomoni, ni alákòóso gbogbo agbègbè Nafati-dori.


Pẹlu ipá ni Solomoni ọba fi kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́, tí ó fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀, ó sì kọ́ Milo, ati odi Jerusalẹmu, ati ìlú Hasori, ìlú Megido ati ìlú Geseri.


Ní àkókò tí Peka jọba Israẹli ni Tigilati Pileseri, ọba Asiria, gba ìlú Ijoni, Abeli Beti Maaka, Janoa, Kedeṣi, Hasori, ati ilẹ̀ Gileadi, Galili ati gbogbo ilẹ̀ Nafutali, ó sì kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rú lọ sí Asiria.


OLUWA o ti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti jẹ àwọn ọ̀tá níyà, ṣugbọn wọn kò rí i. Jẹ́ kí wọn rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn eniyan rẹ jẹ ọ́ lógún, kí ojú sì tì wọ́n. Jẹ́ kí iná tí o dá fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.


Nígbà tí o bá ń la ibú omi kọjá, n óo wà pẹlu rẹ; nígbà tí o bá la odò ńlá kọjá, kò ní bò ọ́ mọ́lẹ̀, nígbà tí o bá ń kọjá ninu iná, kò ní jó ọ. Ahọ́n iná kò ní jó ọ run.


Lẹ́yìn náà, Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pada sí àgọ́ wọn, ní Giligali.


Joṣua bá yipada, ó gba ìlú Hasori, ó sì fi idà pa ọba wọn, nítorí pé Hasori ni olú-ìlú ìjọba ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ rí.


Ṣimironi Meroni ati Akiṣafu,


gbogbo wọn parapọ̀, wọ́n fi ohùn ṣọ̀kan láti bá Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli jagun.


Ṣugbọn Sisera sá lọ sí àgọ́ Jaeli, aya Heberi, ará Keni, nítorí pé alaafia wà ní ààrin Jabini, ọba Hasori, ati ìdílé Heberi ará Keni.


OLUWA bá fi wọ́n lé Jabini ọba Kenaani, tí ó jọba ní Hasori lọ́wọ́; Sisera, tí ń gbé Haroṣeti-ha-goimu ni olórí ogun rẹ̀.


“Ní Taanaki lẹ́bàá odò Megido àwọn ọba wá, wọ́n jagun, wọ́n bá àwọn ọba Kenaani jagun, ṣugbọn wọn kò rí ìkógun fadaka kó.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan