Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 10:8 - Yoruba Bible

8 OLUWA wí fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù wọn, nítorí pé mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní lè ṣẹgun rẹ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru wọn: nitoriti mo ti fi wọn lé ọ lọwọ; ki yio sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn; Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojúkọ ọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 10:8
16 Iomraidhean Croise  

Wolii kan bá tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ‘Ṣé o rí gbogbo àwọn ọmọ ogun yìí bí wọ́n ti pọ̀ tó? Wò ó! N óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn lónìí, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”


Kí ni kí á wá wí sí gbogbo nǹkan wọnyi? Bí Ọlọrun bá wà lẹ́yìn wa, ta ni lè lòdì sí wa?


Ṣugbọn OLUWA wí fún mi pé, ‘Má bẹ̀rù rẹ̀, nítorí pé mo ti fi òun ati àwọn eniyan rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́, ohun tí o ṣe sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé Heṣiboni ni kí o ṣe sí òun náà.’


Yóo fi àwọn ọba wọn lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì pa orúkọ wọn run ní gbogbo ayé, kò ní sí ẹyọ ẹnìkan tí yóo lè dojú kọ yín títí tí ẹ óo fi pa wọ́n run.


Joṣua bá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àyà yín já. Ẹ múra, kí ẹ sì ṣe ọkàn gírí, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀ ń bá jà.”


Joṣua jálù wọ́n lójijì, lẹ́yìn tí ó ti fi gbogbo òru rìn láti Giligali.


OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí pé ní ìwòyí ọ̀la, òkú wọn ni n óo fi lé Israẹli lọ́wọ́. Dídá ni kí ẹ dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, kí ẹ sì sun gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”


OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́, kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ kí o lọ sí ìlú Ai. Wò ó! Mo ti fi ọba Ai, ati àwọn eniyan rẹ̀, ìlú rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.


OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “N óo wà pẹlu rẹ, o óo sì run àwọn ará Midiani bí ẹni pé, ẹyọ ẹnìkan péré ni wọ́n.”


OLUWA sọ fún un ní òru ọjọ́ kan náà pé, “Gbéra, lọ gbógun ti àgọ́ náà, nítorí pé mo ti fi lé ọ lọ́wọ́.


Gbogbo àwọn eniyan wọnyi yóo sì mọ̀ dájú pé OLUWA kò nílò idà ati ọ̀kọ̀ láti gba eniyan là. Ti OLUWA ni ogun yìí, yóo sì gbé mi borí rẹ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan