Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 10:3 - Yoruba Bible

3 Nítorí náà, Adonisedeki ọba Jerusalẹmu ranṣẹ sí Hohamu ọba Heburoni, Piramu ọba Jarimutu, Jafia ọba Lakiṣi ati Debiri ọba Egiloni, pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Nitorina Adoni-sedeki ọba Jerusalemu ranṣẹ si Hohamu ọba Hebroni, ati si Piramu ọba Jarmutu, ati si Jafia ọba Lakiṣi, ati si Debiri ọba Egloni, wipe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nítorí náà Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu bẹ Hohamu ọba Hebroni, Piramu ọba Jarmatu, Jafia ọba Lakiṣi àti Debiri ọba Egloni. Wí pe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 10:3
19 Iomraidhean Croise  

Ó kú ní Kiriati Ariba, ní Heburoni, ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu sọkún, ó sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.


Israẹli sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́, lọ bá mi wo alaafia àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ati ti àwọn agbo ẹran wá, kí o sì tètè pada wá jíṣẹ́ fún mi.” Israẹli bá rán an láti àfonífojì Heburoni lọ sí Ṣekemu.


Ọdún meje ààbọ̀ ni Dafidi fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní ìlú Heburoni.


Hesekaya ranṣẹ sí Senakeribu, ọba Asiria, tí ó wà ní Lakiṣi nígbà náà, ó ní: “Mo ti ṣẹ̀, jọ̀wọ́ dá ọwọ́ ogun rẹ dúró; n óo sì san ohunkohun tí o bá bèèrè.” Ọba náà sì bèèrè fún ọọdunrun ìwọ̀n talẹnti fadaka ati ọgbọ̀n ìwọ̀n talẹnti wúrà lọ́wọ́ Hesekaya ọba Juda.


Ọba Asiria rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀: Tatani, Rabusarisi ati Rabuṣake pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun láti Lakiṣi láti gbógun ti Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu wọ́n dúró sí ibi ọ̀nà tí àwọn tí wọn ń hun aṣọ tí ń ṣiṣẹ́, lẹ́bàá kòtò omi tí ń ṣàn wá láti adágún omi tí ó wà ninu ìlú lápá òkè.


Adoraimu, Lakiṣi, ati Aseka;


ní àkókò tí àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni gbógun ti Jerusalẹmu ati Lakiṣi ati Aseka, nítorí pé àwọn nìkan ni wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn ìlú olódi Juda.


Ẹ̀yin ará Lakiṣi, ẹ de kẹ̀kẹ́ ogun yín mọ́ ẹṣin; ọ̀dọ̀ yín ni ẹ̀ṣẹ̀ ti kọ́ bẹ̀rẹ̀, tí ó sì tàn lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu, nítorí pé nípasẹ̀ yín ni Israẹli ṣe dẹ́ṣẹ̀.


Wọ́n gba ìhà gúsù gòkè lọ sí Heburoni, níbi tí àwọn ẹ̀yà Ahimani, ati ti Ṣeṣai ati ti Talimai, àwọn òmìrán ọmọ Anaki ń gbé. (A ti tẹ Heburoni dó ní ọdún meje ṣáájú Soani ní ilẹ̀ Ijipti.)


Nígbà tí Adonisedeki, ọba Jerusalẹmu, gbọ́ bí Joṣua ṣe gba ìlú Ai, ati pé ó pa ìlú Ai ati ọba rẹ̀ run, bí ó ti ṣe sí ìlú Jẹriko ati ọba rẹ̀; ati pé àwọn ará Gibeoni ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia, wọ́n sì ń gbé ààrin wọn,


Wọ́n bá kó wọn jáde, láti inú ihò: ọba Jerusalẹmu, ọba Heburoni, ọba Jarimutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egiloni.


Joṣua kúrò ní Lakiṣi, ó lọ sí Egiloni pẹlu gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dó ti Egiloni, wọ́n sì bá a jagun.


Nígbà náà ni àwọn ọba Amori maraarun, ọba Jerusalẹmu, ti Heburoni, ti Jarimutu, ti Lakiṣi, ati ti Egiloni parapọ̀, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ. Wọ́n lọ dó ti Gibeoni, wọ́n sì ń bá a jagun.


Orúkọ Heburoni tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Ariba; Ariba yìí ni ẹni tí ó jẹ́ alágbára jùlọ ninu àwọn òmìrán tí à ń pè ní Anakimu. Àwọn eniyan náà sì sinmi ogun jíjà ní ilẹ̀ náà.


Kiriati Ariba (tí à ń pè ní Heburoni), ati Siori, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹsan-an.


Ṣugbọn àwọn eniyan Juda kò lè lé àwọn Jebusi tí wọn ń gbé inú ilẹ̀ Jerusalẹmu jáde. Àwọn Jebusi yìí sì tún wà láàrin àwọn eniyan Juda ní Jerusalẹmu títí di òní olónìí.


Sela, Haelefi, Jebusi (tí à ń pè ní Jerusalẹmu) Gibea, ati Kiriati Jearimu, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrinla. Ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan