Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 10:12 - Yoruba Bible

12 Ní ọjọ́ tí OLUWA fi àwọn ará Amori lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, Joṣua bá OLUWA sọ̀rọ̀ lójú gbogbo Israẹli, ó ní, “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní Gibeoni. Ìwọ òṣùpá, sì dúró jẹ́ẹ́ ní àfonífojì Aijaloni.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Nigbana ni Joṣua wi fun OLUWA li ọjọ́ ti OLUWA fi awọn Amori fun awọn ọmọ Israeli, o si wi li oju Israeli pe, Iwọ, Õrùn, duro jẹ lori Gibeoni; ati Iwọ, Oṣupa, li afonifoji Aijaloni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ní ọjọ́ tí Olúwa fi àwọn ọmọ Amori lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sọ fún Olúwa níwájú àwọn ará Israẹli: “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gibeoni, Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí Àfonífojì Aijaloni.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 10:12
29 Iomraidhean Croise  

Abineri ọmọ Neri ati àwọn iranṣẹ Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ṣígun láti Mahanaimu, lọ sí ìlú Gibeoni.


Hesekaya dáhùn pé, “Ó rọrùn fún òjìji láti lọ siwaju ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá, kí ó pada sẹ́yìn ni mo fẹ́.”


Aisaya gbadura sí OLUWA, OLUWA sì mú kí òjìji pada sẹ́yìn ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá lára àtẹ̀gùn ilé tí ọba Ahasi ṣe.


Aisaya dáhùn pé, “OLUWA yóo fún ọ ní àmì láti fihàn pé òun yóo mú ìlérí òun ṣẹ. Èwo ni o fẹ́, ninu kí òjìji lọ siwaju ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá tabi kí ó pada sẹ́yìn ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá?”


Beraya ati Ṣema ni olórí àwọn ìdílé tí wọn ń gbé ìlú Aijaloni, àwọn sì ni wọ́n lé àwọn tí wọn ń gbé ìlú Gati tẹ́lẹ̀ kúrò;


Sora, Aijaloni ati Heburoni. Àwọn ni ìlú olódi ní Juda ati Bẹnjamini.


Ó pàṣẹ fún oòrùn, oòrùn kò sì yọ; ó sé àwọn ìràwọ̀ mọ́lé;


Ẹ yìn ín, oòrùn ati òṣùpá; ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ tí ń tàn.


sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já, ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé. Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run,


Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ náà sì ni òru, ìwọ ni o gbé òṣùpá ati oòrùn ró.


Nítorí pé OLUWA yóo dìde bí ó ti ṣe ní òkè Firasi, yóo bínú bí ó ti bínú ní àfonífojì Gibeoni. Yóo ṣe ohun tí ó níí ṣe, ohun tí yóo ṣe yóo jọni lójú; yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ yóo ṣe àjèjì.


Òun óo mú kí òjìji oòrùn ìrọ̀lẹ́ pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi. Oòrùn bá yí pada nítòótọ́, òjìji sì pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀.


Oòrùn rẹ kò ní wọ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá rẹ kò ní wọ òkùnkùn. Nítorí OLUWA ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ, ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ yóo sì dópin.


Ní ọdún kan náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda, ní oṣù karun-un ọdún kẹrin, Hananaya wolii ọmọ Aṣuri, tí ó wá láti Gibeoni bá mi sọ̀rọ̀ ní ilé OLUWA lójú àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan pé,


“Bẹ́ẹ̀ sì ni èmi ni mo pa àwọn ará Amori run fún wọn, àwọn géńdé, tí wọ́n ga bí igi kedari, tí wọ́n sì lágbára bí igi oaku; mo run wọ́n tèsotèso, tigbòǹgbò-tigbòǹgbò.


Ní ọjọ́ náà, n óo mú kí oòrùn wọ̀ ní ọjọ́kanrí, ilẹ̀ yóo sì ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan.


Ṣugbọn OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀, kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ̀.


Oòrùn ati òṣùpá dúró ní ipò wọn, nígbà tí ọfà rẹ ń já lọ ṣòòrò, tí àwọn ọ̀kọ̀ rẹ náà ń kọ mànà, bí wọ́n ti ń fò lọ.


Ẹ̀yin eniyan, ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA, nítorí ó ń jáde bọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀.


bí ó bá lọ bọ oriṣa, kì báà ṣe oòrùn, tabi òṣùpá, tabi ọ̀kan ninu àwọn nǹkan mìíràn tí ó wà ní ojú ọ̀run, tí mo ti pàṣẹ pé ẹ kò gbọdọ̀ bọ;


Ẹ ṣọ́ra nígbà tí ẹ bá gbé ojú yín sókè sí ojú ọ̀run, tí ẹ bá rí oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, ati ogunlọ́gọ̀ àwọn ohun tí ó wà ní ojú ọ̀run, kí ọkàn yín má baà fà sí wọn, kí ẹ sì máa bọ àwọn ohun tí OLUWA Ọlọrun yín fún gbogbo eniyan láyé.


Oòrùn bá dúró jẹ́ẹ́, òṣùpá náà sì dúró jẹ́ẹ́, títí tí àwọn ọmọ Israẹli fi gbẹ̀san tán lára àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n kọ ọ́ sinu ìwé Jaṣari pé, oòrùn dúró ní agbede meji ojú ọ̀run, kò sì tètè wọ̀ fún bí odidi ọjọ́ kan.


Ṣaalibimu, Aijaloni, Itila,


Aijaloni ati Gati Rimoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.


Nígbà tí Eloni ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Aijaloni ní ilẹ̀ Sebuluni.


Láti ojú ọ̀run ni àwọn ìràwọ̀ ti ń jagun, àní láti ààyè wọn lójú ọ̀nà wọn, ni wọ́n ti bá Sisera jà.


Samuẹli bá gbadura, ní ọjọ́ náà gan-an, OLUWA sán ààrá, ó sì rọ òjò. Ẹ̀rù OLUWA ati ti Samuẹli sì ba gbogbo àwọn eniyan náà.


Wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Filistini ní ọjọ́ náà, láti Mikimaṣi títí dé Aijaloni; ó sì rẹ àwọn eniyan náà gidigidi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan