Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 10:10 - Yoruba Bible

10 OLUWA mú kí ìpayà bá àwọn ará Amori, nígbà tí wọ́n rí àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọmọ Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Wọ́n lé wọn gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Beti Horoni, wọ́n sì pa wọ́n títí dé Aseka ati Makeda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 OLUWA si fọ́ wọn niwaju Israeli, o si pa wọn ni ipakupa ni Gibeoni, o si lepa wọn li ọ̀na òke Beti-horoni, o si pa wọn dé Aseka, ati dé Makkeda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Olúwa mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Israẹli, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Israẹli sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Beti-Horoni, ó sì pa wọ́n dé Aseka, àti Makkeda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 10:10
29 Iomraidhean Croise  

Ó ta ọpọlọpọ ọfà, ó sì tú wọn ká. Ó tan mànàmáná, wọ́n sì ń sá.


Nítorí náà ni Solomoni ṣe tún ìlú náà kọ́.) Pẹlu apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni,


Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe ṣẹgun àwọn ará Etiopia fún Asa ati àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Etiopia sì sá.


Àwọn ọmọ ogun Israẹli tí Amasaya dá pada, tí kò jẹ́ kí wọ́n tẹ̀lé òun lọ sógun bá lọ, wọ́n kọlu àwọn ìlú Juda láti Samaria títí dé Beti Horoni. Wọ́n pa ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun.


Ó ta ọfà rẹ̀ jáde, ó sì fọ́n wọn ká, ó jẹ́ kí mànàmáná kọ, ó sì tú wọn ká.


Nítorí pé kì í ṣe idà wọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà, kì í ṣe agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun; agbára rẹ ni; àní, agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ati ojurere rẹ; nítorí pé inú rẹ dùn sí wọn.


Nígbà tí Olodumare tú àwọn ọba ká, ní òkè Salimoni, yìnyín bọ́.


Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde kí wọn ó tó dé ibẹ̀; ó pín ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn bí ohun ìní; ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli jókòó ninu àgọ́ wọn.


Nítorí pé OLUWA yóo dìde bí ó ti ṣe ní òkè Firasi, yóo bínú bí ó ti bínú ní àfonífojì Gibeoni. Yóo ṣe ohun tí ó níí ṣe, ohun tí yóo ṣe yóo jọni lójú; yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ yóo ṣe àjèjì.


OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ó lógo, yóo sì jẹ́ kí ẹ rí ọwọ́ rẹ̀ tí yóo fà yọ pẹlu ibinu ńlá ati ninu iná ajónirun; pẹlu ẹ̀fúùfù ati ìjì líle ati òjò yìnyín.


ní àkókò tí àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni gbógun ti Jerusalẹmu ati Lakiṣi ati Aseka, nítorí pé àwọn nìkan ni wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn ìlú olódi Juda.


OLUWA yóo wá jáde, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jà, bí ìgbà tí ó ń jà lójú ogun.


Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, yóo sì mú kí ìdàrúdàpọ̀ bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin wọn títí tí wọn yóo fi parun.


Bí wọ́n sì ti ń sá lọ fún àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ ní ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Beti Horoni, OLUWA mú kí àwọn òkúta ńláńlá máa bọ́ lù wọ́n láti ojú ọ̀run, títí tí wọ́n fi dé Aseka, wọ́n sì kú. Àwọn tí òkúta ńláńlá wọnyi pa pọ̀ ju àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa lọ.


Ní ọjọ́ náà gan-an ni Joṣua gba ìlú Makeda, ó sì fi idà pa àwọn eniyan inú rẹ̀ ati ọba wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ ni ó parun, kò dá ẹnikẹ́ni sí. Bí ó ti ṣe sí ọba Jẹriko náà ló ṣe sí ọba Makeda.


Joṣua jálù wọ́n lójijì, lẹ́yìn tí ó ti fi gbogbo òru rìn láti Giligali.


OLUWA fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n. Wọ́n lé wọn títí dé Sidoni ati Misirefoti Maimu, ati apá ìlà oòrùn títí dé àfonífojì Misipa, wọ́n pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan.


Makeda ati Bẹtẹli,


Jarimutu, Adulamu, Soko, Aseka;


Beti Dagoni, Naama, ati Makeda; gbogbo ìlú ati ìletò wọ́n jẹ́ mẹrindinlogun.


Bákan náà ni ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn títí dé agbègbè àwọn ará Jafileti, títí dé apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni. Ó tún lọ láti ibẹ̀ títí dé Geseri, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia.


Èyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Efuraimu gbà, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ààlà ilẹ̀ wọn ní apá ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ láti Atarotu Adari, títí dé apá òkè Beti Horoni.


Kibusaimu ati Beti Horoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.


OLUWA mú ìdàrúdàpọ̀ bá Sisera ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ níwájú Baraki. Bí àwọn ọmọ ogun Baraki ti ń fi idà pa wọ́n, Sisera sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ.


Baraki lépa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun Sisera títí dé Haroṣeti-ha-goimu, wọ́n sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun Sisera láìku ẹyọ ẹnìkan.


Láti ojú ọ̀run ni àwọn ìràwọ̀ ti ń jagun, àní láti ààyè wọn lójú ọ̀nà wọn, ni wọ́n ti bá Sisera jà.


àwọn kan lọ sí apá ọ̀nà Beti Horoni, àwọn yòókù lọ sí ẹ̀bá ìpínlẹ̀ àtiwọ àfonífojì Seboimu ní ọ̀nà aṣálẹ̀.


Àwọn ọmọ ogun Filistini kó ara wọn jọ sí Soko, ìlú kan ní ilẹ̀ Juda láti bá Israẹli jagun. Wọ́n pa ibùdó wọn sí Efesi Damimu, tí ó wà láàrin Soko ati Aseka.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan