Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 10:1 - Yoruba Bible

1 Nígbà tí Adonisedeki, ọba Jerusalẹmu, gbọ́ bí Joṣua ṣe gba ìlú Ai, ati pé ó pa ìlú Ai ati ọba rẹ̀ run, bí ó ti ṣe sí ìlú Jẹriko ati ọba rẹ̀; ati pé àwọn ará Gibeoni ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia, wọ́n sì ń gbé ààrin wọn,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O SI ṣe, nigbati Adoni-sedeki ọba Jerusalemu gbọ́ pe Joṣua ti kó Ai, ti o si pa a run patapata; bi o ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀, bẹ̃li o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀; ati bi awọn ara Gibeoni ti bá Israeli ṣọrẹ, ti nwọn si ngbé ãrin wọn;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní báyìí tí Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu gbọ́ pé Joṣua ti gba Ai, tí ó sì ti pa wọ́n pátápátá; tí ó sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, àti bí àwọn ènìyàn Gibeoni ti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Israẹli, tí wọ́n sì ń gbé nítòsí wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 10:1
10 Iomraidhean Croise  

Mẹlikisẹdẹki ọba Salẹmu náà mú oúnjẹ ati ọtí waini wá pàdé rẹ̀. Mẹlikisẹdẹki jẹ́ alufaa Ọlọrun Ọ̀gá Ògo.


Nítorí Mẹlikisẹdẹki yìí jẹ́ ọba Salẹmu ati alufaa Ọlọrun Ọ̀gá Ògo. Òun ni ó pàdé Abrahamu nígbà tí Abrahamu ń pada bọ̀ láti ojú-ogun lẹ́yìn tí ó bá ọba mẹrin jà, tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa. Ó bá súre fún Abrahamu.


Nítorí náà, Adonisedeki ọba Jerusalẹmu ranṣẹ sí Hohamu ọba Heburoni, Piramu ọba Jarimutu, Jafia ọba Lakiṣi ati Debiri ọba Egiloni, pé,


Wọ́n run gbogbo àwọn ará ìlú náà patapata: atọkunrin, atobinrin, àtọmọdé, àtàgbà, àtakọ mààlúù, ataguntan, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; gbogbo wọn ni wọ́n fi idà parun.


Bí o ti ṣe sí Jẹriko ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe sí Ai ati ọba rẹ̀. Ṣugbọn ẹ dá ìkógun ati àwọn ẹran ọ̀sìn tí ó wà níbẹ̀ sí, kí ẹ sì kó o gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín; ẹ ba ní ibùba lẹ́yìn odi ìlú náà.”


Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn tí wọn farapamọ́ ti gba ìlú náà, tí èéfín sì ti yọ sókè, wọ́n yipada, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ará Ai.


Ṣugbọn nígbà tí àwọn ará Gibeoni gbọ́ ohun tí Joṣua ṣe sí ìlú Jẹriko ati Ai,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan