Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 1:8 - Yoruba Bible

8 Máa ka ìwé òfin yìí nígbà gbogbo, kí o sì máa ṣe àṣàrò ninu rẹ̀, tọ̀sán-tòru; rí i dájú pé o pa gbogbo ohun tí wọ́n kọ sinu rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni yóo dára fún ọ, gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé yóo sì máa yọrí sí rere.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Iwé ofin yi kò gbọdọ kuro li ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o ma ṣe àṣaro ninu rẹ̀ li ọsán ati li oru, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu rẹ̀: nitori nigbana ni iwọ o ṣe ọ̀na rẹ ni rere, nigbana ni yio si dara fun ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Má ṣe jẹ́ kí Ìwé Ofin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 1:8
40 Iomraidhean Croise  

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó lọ ṣe àṣàrò ninu pápá, ojú tí ó gbé sókè, ó rí i tí àwọn ràkúnmí ń bọ̀.


Ó sin Ọlọrun nígbà ayé Sakaraya, nítorí pé Sakaraya ń kọ́ ọ ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. Ní gbogbo àkókò tí ó fi ń sin Ọlọrun, Ọlọrun bukun un.


Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn, kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.


N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ, n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ.


Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ! Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru.


Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ, nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò.


Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ati àṣàrò ọkàn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, OLUWA ibi ààbò mi ati olùràpadà mi.


Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́. Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ; n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ninu àwùjọ ńlá.


Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ, sì pa òfin mi mọ́ lọ́kàn rẹ,


“Majẹmu tí Èmi bá wọn dá nìyí: Ẹ̀mí mi tí mo fi le yín lórí, ati ọ̀rọ̀ mi tí mo fi si yín lẹ́nu, kò gbọdọ̀ kúrò lẹ́nu yín, ati lẹ́nu àwọn ọmọ rẹ, ati lẹ́nu arọmọdọmọ yín, láti àkókò yìí lọ ati títí laelae. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


Ẹni rere a máa sọ ọ̀rọ̀ rere jáde láti inú ìṣúra rere; eniyan burúkú a sì máa sọ ọ̀rọ̀ burúkú jáde láti inú ìṣúra burúkú.


Ẹ máa kọ́ wọn láti kíyèsí gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Kí ẹ mọ̀ dájú pé mo wà pẹlu yín ní ìgbà gbogbo, títí dé òpin ayé.”


“Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ń pè mí ní, ‘Oluwa, Oluwa’ ni yóo wọ ìjọba ọ̀run, bíkòṣe àwọn tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run.


“Nítorí náà, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí ó bá fi ṣe ìwà hù dàbí ọlọ́gbọ́n eniyan kan, tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta.


Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Èyí tí ó jù ni pé àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń pa á mọ́ ṣe oríire.”


Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.


“Ẹni tí ó bá gba òfin mi, tí ó sì pa wọ́n mọ́, òun ni ó fẹ́ràn mi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn mi, Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi náà yóo fẹ́ràn rẹ̀, n óo sì fi ara mi hàn án.”


Ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ kankan kò gbọdọ̀ ti ẹnu yín jáde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rere, tí ó lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ nígbàkúùgbà ni kí ẹ máa sọ jáde lẹ́nu. Èyí yóo ṣe àwọn tí ó bá gbọ́ ní anfaani.


A gba ilẹ̀ wọn, a sì fi fún ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn.


Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ máa tẹ̀lé majẹmu yìí, kí ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé lè máa yọrí sí rere.


Ṣugbọn nítòsí yín ni ọ̀rọ̀ náà wà, ó wà lẹ́nu yín, ó sì wà ninu ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé ẹ lè ṣe é.


nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sin OLUWA ní ibi tí ó yàn pé kí wọ́n ti máa sin òun, o gbọdọ̀ máa ka òfin yìí sí etígbọ̀ọ́ gbogbo wọn.


Nígbà tí Mose kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé òfin yìí tán patapata,


Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbọ́ àwọn ìlànà ati àwọn òfin tí n óo kà fun yín lónìí; ẹ kọ́ wọn, kí ẹ sì rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀lé wọn.


Yóo ti dára tó, bí wọ́n bá ní irú ẹ̀mí yìí nígbà gbogbo, kí wọ́n bẹ̀rù mi, kí wọ́n sì pa gbogbo òfin mi mọ́, kí ó lè dára fún wọn, ati fún àwọn ọmọ wọn títí lae.


“Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fun yín; ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìgbọràn ninu ohunkohun.


Kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kí ẹ máa fi gbogbo ọgbọ́n kọ́ ara yín, kí ẹ máa fún ara yín ní ìwúrí nípa kíkọ Orin Dafidi, ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá. Ẹ máa kọrin sí Ọlọrun pẹlu ọpẹ́ ninu ọkàn yín.


Ìwọ ṣá ti múra, kí o ṣe ọkàn gírí, kí o sì rí i dájú pé o pa gbogbo òfin tí Mose, iranṣẹ mi, fún ọ mọ́. Má ṣe yẹsẹ̀ kúrò ninu rẹ̀ sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé níbikíbi tí o bá lọ lè máa yọrí sí rere.


Lẹ́yìn náà Joṣua ka gbogbo òfin náà sókè ati ibukun tí ó wà ninu rẹ̀, ati ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin.


Àwọn tí wọ́n bá fọ aṣọ wọn ṣe oríire. Wọn óo ní àṣẹ láti dé ibi igi ìyè, wọn óo sì gba ẹnu ọ̀nà wọ inú ìlú mímọ́ náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan