Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 1:7 - Yoruba Bible

7 Ìwọ ṣá ti múra, kí o ṣe ọkàn gírí, kí o sì rí i dájú pé o pa gbogbo òfin tí Mose, iranṣẹ mi, fún ọ mọ́. Má ṣe yẹsẹ̀ kúrò ninu rẹ̀ sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé níbikíbi tí o bá lọ lè máa yọrí sí rere.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Sá ṣe giri ki o si mu àiya le gidigidi, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi ti palaṣẹ fun ọ: má ṣe yà kuro ninu rẹ̀ si ọtún tabi si òsi, ki o le dara fun ọ nibikibi ti iwọ ba lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, Má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 1:7
25 Iomraidhean Croise  

“Ó tó àkókò fún mi, láti lọ sí ibi tí àgbà ń rè. Mú ọkàn gírí kí o sì ṣe bí ọkunrin.


Ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ pé kí o ṣe, máa tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀, sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ sinu ìwé òfin Mose, kí gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lè máa yọrí sí rere, níbikíbi tí o bá n lọ.


Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ó tẹ̀ sí ọ̀nà Dafidi, baba ńlá rẹ̀, kò sì ṣe nǹkankan tí ó lòdì sí àpẹẹrẹ tí Dafidi fi lélẹ̀.


Bí o bá pa gbogbo òfin tí Ọlọrun fún Israẹli láti ọwọ́ Mose mọ́, o óo ṣe rere. Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́.


Ṣugbọn, ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ mọ́kàn le, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó rẹ̀ yín, nítorí iṣẹ́ yín yóo ní èrè.”


Ó sin Ọlọrun nígbà ayé Sakaraya, nítorí pé Sakaraya ń kọ́ ọ ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. Ní gbogbo àkókò tí ó fi ń sin Ọlọrun, Ọlọrun bukun un.


OLUWA tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí ẹni tí ó jẹ́ olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé, ati pé ó bẹ̀rù èmi OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú?”


Mú wa bọ̀ sípò, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun! Fi ojurere wò wá, kí á lè là!


Má ṣe yà sí ọ̀tún tabi sí òsì, yipada kúrò ninu ibi.


Ọ̀nà òdodo ni èmi ń rìn, ojú ọ̀nà tí ó tọ́ ni mò ń tọ̀.


Ó ní, “Ìwọ tí Ọlọrun fẹ́ràn, má bẹ̀rù, alaafia ni, dá ara yá, kí o sì ṣe ọkàn gírí.” Nígbà tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo tún lágbára sí i; mo bá dáhùn pé, “olúwa mi, máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ lọ, nítorí ìwọ ni ó fún mi lágbára sí i.”


ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, ó sì fún un ní àṣẹ.


“Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́ kí ẹ lè ní agbára tó láti gba ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ láti gbà.


“Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fun yín ni kí ẹ fọkàn sí, kí ẹ sì ṣe é, ẹ kò gbọdọ̀ fi kún un, ẹ kò sì gbọdọ̀ mú kúrò ninu rẹ̀.


tí o kò bá yipada ninu àwọn òfin tí mo ṣe fún ọ lónìí, tí o kò sì sá tọ àwọn oriṣa lọ, láti máa bọ wọ́n.


A gba ilẹ̀ wọn, a sì fi fún ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn.


Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ máa tẹ̀lé majẹmu yìí, kí ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé lè máa yọrí sí rere.


Mose bá pe Joṣua, ó sọ fún un níwájú gbogbo àwọn eniyan Israẹli, pé, “Múra gírí, kí o sì mú ọkàn gidigidi nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn eniyan wọnyi lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun ti búra fún àwọn baba wọn pé òun yóo fi fún wọn. Ìwọ ni o óo sì fi lé wọn lọ́wọ́.


Ẹ kò gbọdọ̀ fi kún òfin tí mo fun yín yìí, ẹ kò sì gbọdọ̀ mú kúrò ninu rẹ̀, kí ẹ lè máa pa òfin OLUWA Ọlọrun yín tí mo fun yín mọ́.


“Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fun yín; ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìgbọràn ninu ohunkohun.


Lẹ́yìn ikú Mose, iranṣẹ OLUWA, OLUWA sọ fún Joṣua, ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ Mose pé,


Máa ka ìwé òfin yìí nígbà gbogbo, kí o sì máa ṣe àṣàrò ninu rẹ̀, tọ̀sán-tòru; rí i dájú pé o pa gbogbo ohun tí wọ́n kọ sinu rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni yóo dára fún ọ, gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé yóo sì máa yọrí sí rere.


Ranti pé mo ti pàṣẹ fún ọ pé kí o múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn rẹ, nítorí pé èmi, OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ níbikíbi tí o bá ń lọ.”


Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, iranṣẹ rẹ̀, ni Mose náà ṣe pàṣẹ fún Joṣua, tí Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ohunkohun sílẹ̀ láìṣe, ninu gbogbo nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose.


Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sinu ìwé òfin Mose. Ẹ kò gbọdọ̀ yẹ ẹsẹ̀ kúrò ninu wọn sí ọ̀tún tabi sí òsì,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan