Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 1:6 - Yoruba Bible

6 Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, nítorí ìwọ ni o óo jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn, pé n óo fún wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitori iwọ ni yio pín ilẹ na fun awọn enia yi, ilẹ ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 “Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 1:6
36 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni OLUWA fara han Abramu, ó wí pé, “Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA tí ó fara hàn án.


Ọlọrun ní, “Máa gbé ilẹ̀ yìí, n óo wà pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ, nítorí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún ní ilẹ̀ wọnyi, n óo sì mú ìlérí mi fún Abrahamu, baba rẹ ṣẹ.


Múra gírí, jẹ́ kí á fi gbogbo agbára wa jà fún àwọn eniyan wa ati fún ìlú Ọlọrun wa. Kí OLUWA wa ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.”


“Ó tó àkókò fún mi, láti lọ sí ibi tí àgbà ń rè. Mú ọkàn gírí kí o sì ṣe bí ọkunrin.


Bí o bá pa gbogbo òfin tí Ọlọrun fún Israẹli láti ọwọ́ Mose mọ́, o óo ṣe rere. Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́.


Kíyèsára, nítorí pé OLUWA ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé kan tí yóo jẹ́ ibi mímọ́, ṣe gírí, kí o sì kọ́ ọ.”


Dafidi bá sọ fún Solomoni, ọmọ rẹ̀ pé, “Múra gírí, mú ọkàn le, kí o sì ṣe bí mo ti wí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì; nítorí OLUWA Ọlọrun, àní Ọlọrun mi, wà pẹlu rẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀, títí tí iṣẹ́ ilé OLUWA yóo fi parí.


Ṣugbọn, ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ mọ́kàn le, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó rẹ̀ yín, nítorí iṣẹ́ yín yóo ní èrè.”


Wò ó! Wọ́n ń fi burúkú san ire fún wa, wọ́n ń bọ̀ wá lé wa kúrò lórí ilẹ̀ rẹ, tí o fún wa bí ìní.


Ṣebí ìwọ, Ọlọrun wa, ni o lé gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ kúrò fún àwa ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, tí o sì fi ilẹ̀ náà fún arọmọdọmọ Abrahamu, ọ̀rẹ́ rẹ, títí lae?


Dúró de OLUWA, ṣe bí akin, kí o sì mú ọkàn gírí, àní, dúró de OLUWA.


Ó ní, “Ìwọ tí Ọlọrun fẹ́ràn, má bẹ̀rù, alaafia ni, dá ara yá, kí o sì ṣe ọkàn gírí.” Nígbà tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo tún lágbára sí i; mo bá dáhùn pé, “olúwa mi, máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ lọ, nítorí ìwọ ni ó fún mi lágbára sí i.”


Ṣugbọn, mú ọkàn le, ìwọ Serubabeli, má sì fòyà, ìwọ Joṣua, ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa; ẹ ṣe ara gírí kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ náà ẹ̀yin eniyan; nítorí mo wà pẹlu yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí.


OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ ṣara gírí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii tí ń sọ láti ìgbà tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun lélẹ̀, kí ẹ baà lè kọ́ ilé náà parí.


“Àwọn wọnyi ni kí o pín ilẹ̀ náà fún gẹ́gẹ́ bí iye wọn.


Kí ẹ gba ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa gbé inú rẹ̀, nítorí pé mo ti fun yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní yín.


Ẹ máa ṣọ́nà. Ẹ dúró gbọningbọnin ninu igbagbọ. Ẹ ṣe bí ọkunrin. Ẹ jẹ́ alágbára.


Ní ìparí, ẹ jẹ́ alágbára ninu Oluwa, kí ẹ fi agbára rẹ̀ ṣe okun yín.


ilẹ̀ náà ni OLUWA Ọlọrun yín tẹ́ kalẹ̀ níwájú yín yìí, mo ní kí ẹ gbéra, kí ẹ lọ gbà á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín ti sọ fun yín. Mo ní kí ẹ má bẹ̀rù rárá, kí ẹ má sì fòyà.


Ó ní, ‘Ẹ wò ó! Mo ti pèsè ilẹ̀ náà fun yín, ẹ lọ, kí ẹ sì gbà á; Èmi OLUWA ti búra láti fún Abrahamu ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba ńlá yín ati arọmọdọmọ wọn.’ ”


“Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́ kí ẹ lè ní agbára tó láti gba ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ láti gbà.


OLUWA fi iṣẹ́ lé Joṣua ọmọ Nuni lọ́wọ́, ó ní, “Múra gírí kí o sì mú ọkàn gidigidi, nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn ọmọ Israẹli wọ ilẹ̀ tí mo ti búra láti fún wọn. N óo wà pẹlu rẹ.”


Nítorí náà, ìwọ ọmọ mi, jẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ tí ó wà ninu ìdàpọ̀ pẹlu Kristi Jesu sọ ọ́ di alágbára.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí àṣẹ rẹ, tí ó sì kọ̀ láti ṣe ohunkohun tí o bá sọ fún un, pípa ni a óo pa á. Ìwọ ṣá ti múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí.”


Ìwọ ṣá ti múra, kí o ṣe ọkàn gírí, kí o sì rí i dájú pé o pa gbogbo òfin tí Mose, iranṣẹ mi, fún ọ mọ́. Má ṣe yẹsẹ̀ kúrò ninu rẹ̀ sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé níbikíbi tí o bá lọ lè máa yọrí sí rere.


Ranti pé mo ti pàṣẹ fún ọ pé kí o múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn rẹ, nítorí pé èmi, OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ níbikíbi tí o bá ń lọ.”


Joṣua bá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àyà yín já. Ẹ múra, kí ẹ sì ṣe ọkàn gírí, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀ ń bá jà.”


Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, láti Lẹbanoni, títí dé Misirefoti Maimu, ati gbogbo àwọn ará Sidoni ni n óo lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn, ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, bí mo ti pàṣẹ fun yín.


Joṣua bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ìgbà wo ni ẹ fẹ́ dúró dà kí ẹ tó lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fun yín.


Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n gba ilẹ̀ náà tán, wọ́n ń gbé ibẹ̀.


Nítorí pé ogoji ọdún ni àwọn ọmọ Israẹli fi ń rìn kiri láàrin aṣálẹ̀, títí tí àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti Ijipti fi parun tán, nítorí wọn kò gbọ́ ti OLUWA wọn. OLUWA sì ti búra pé, òun kò ní jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀ tí òun ti búra láti fún àwọn baba wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.


Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, ẹ̀yin ọmọ ogun Filistini! Ẹ ṣe bí akọni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a óo di ẹrú àwọn ará Heberu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ẹrú wa, nítorí náà, ẹ ṣe bí akọni, kí ẹ sì jà.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan