Joṣua 1:5 - Yoruba Bible5 Kò ní sí ẹni tí yóo lè borí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bí mo ti wà pẹlu Mose ni n óo wà pẹlu rẹ. N kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lae. Faic an caibideilBibeli Mimọ5 Ki yio sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo: gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o si wà pẹlu rẹ: Emi ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃li emi ki yio kọ̀ ọ. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní5 Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́. Faic an caibideil |
Tí o bá fetí sí gbogbo ohun tí òun pa láṣẹ fún ọ, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà òun, tí ò ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú òun, tí o pa òfin òun mọ́ tí o sì ń mú àṣẹ òun ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, iranṣẹ òun ti ṣe, ó ní òun óo wà pẹlu rẹ, arọmọdọmọ rẹ ni yóo máa jọba lẹ́yìn rẹ, òun óo fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ bí òun ti ṣe fún Dafidi; òun óo sì fi Israẹli fún ọ.