Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 1:4 - Yoruba Bible

4 Láti inú aṣálẹ̀ ati òkè Lẹbanoni yìí lọ, títí dé odò ńlá náà, odò Yufurate, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Hiti, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn, ni yóo jẹ́ ilẹ̀ yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Lati aginjù, ati Lebanoni yi, ani titi dé odò nla nì, odò Euferate, gbogbo ilẹ awọn Hitti, ati titi dé okun nla ni ìwọ-õrùn, eyi ni yio ṣe opin ilẹ nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti aginjù Lebanoni, àti láti odò ńlá, ti Eufurate—gbogbo orílẹ̀-èdè Hiti títí ó fi dé Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 1:4
12 Iomraidhean Croise  

Ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli fadaka ni wọ́n máa ń ra kẹ̀kẹ́ ogun kan láti Ijipti, wọn a sì máa ra ẹṣin kan ní aadọjọ (150) ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Àwọn oníṣòwò Solomoni níí máa ń tà wọ́n fún àwọn ọba ilẹ̀ Hiti ati àwọn ọba ilẹ̀ Siria.


Solomoni jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, láti odò Yufurate títí dé ilẹ̀ Filistia, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Ijipti. Wọ́n ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un, wọ́n sì ń sìn ín ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.


Ó ṣẹgun Hadadeseri, ọba Siria ní Soba, ní agbègbè ilẹ̀ Hamati, bí Hadadeseri tí ń lọ fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Yufurate.


Ilẹ̀ wọn lọ ní apá ìlà oòrùn títí dé àtiwọ aṣálẹ̀, ati títí dé odò Yufurate, nítorí pé ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ ní ilẹ̀ Gileadi.


Àwọn ọba alágbára ti jẹ ní Jerusalẹmu, wọ́n ti jọba lórí gbogbo agbègbè òdìkejì odò, wọ́n sì gba owó ìṣákọ́lẹ̀, owó bodè lọ́wọ́ àwọn eniyan.


Ilẹ̀ yín yóo lọ títí kan Òkun Pupa, ati títí lọ kan òkun àwọn ará Filistia, láti aṣálẹ̀ títí lọ kan odò Yufurate, nítorí pé n óo fi àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà le yín lọ́wọ́, ẹ óo sì lé wọn jáde.


Ó ní kí á dìde, kí á bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí agbègbè olókè ti àwọn ará Amori, ati gbogbo agbègbè tí ó yí wọn ká ní Araba, ní àwọn agbègbè olókè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, ati èyí tí ó wà létí òkun tí wọn ń pè ní Mẹditarenia, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Lẹbanoni, títí dé odò ńlá nnì, àní odò Yufurate.


Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀, ẹ̀yin ni ẹ óo ni ín. Ilẹ̀ yín yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Lẹbanoni, ati láti odò Yufurate títí dé Òkun tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn.


Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí n kọjá sí òdìkejì Jọdani kí n sì rí ilẹ̀ dáradára náà, agbègbè olókè dáradára nnì ati Lẹbanoni.’


Ó sọ fún angẹli kẹfa tí ó mú kàkàkí lọ́wọ́ pé, “Dá àwọn angẹli mẹrin tí a ti dè ní odò ńlá Yufurate sílẹ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan