Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 1:1 - Yoruba Bible

1 Lẹ́yìn ikú Mose, iranṣẹ OLUWA, OLUWA sọ fún Joṣua, ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ Mose pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O si ṣe lẹhin ikú Mose iranṣẹ OLUWA, li OLUWA sọ fun Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, wipe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Lẹ́yìn ikú u Mose ìránṣẹ́ Olúwa, Olúwa sọ fún Joṣua ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ ọ Mose:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 1:1
29 Iomraidhean Croise  

Yan Jehu, ọmọ Nimṣi, ní ọba Israẹli, kí o sì yan Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ará Abeli Mehola, ní wolii dípò ara rẹ.


Ó bá bèèrè pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA kan níhìn-ín tí ó lè bá wa wádìí lọ́wọ́ OLUWA?” Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Joramu bá dáhùn pé, “Eliṣa ọmọ Ṣafati, tí ó jẹ́ iranṣẹ Elija, wà níhìn-ín.”


Gbogbo àpéjọ àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú pa àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn. Láti ìgbà ayé Joṣua ọmọ Nuni, títí di àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli kò pàgọ́ bẹ́ẹ̀ rí, gbogbo wọn sì yọ ayọ̀ ńlá.


Mose bá gbéra, òun ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ó gun orí òkè Ọlọrun lọ.


Nígbà náà ni Joṣua, ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, ọ̀kan ninu àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ wí fún Mose pé, “Pa wọ́n lẹ́nu mọ́.”


Ṣugbọn ti Mose, iranṣẹ mi yàtọ̀. Mo ti fi ṣe alákòóso àwọn eniyan mi.


Orúkọ àwọn ọkunrin tí Mose rán láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà nìyí. Mose sì yí orúkọ Hoṣea ọmọ Nuni pada sí Joṣua.


láti inú ẹ̀yà Efuraimu, ó rán Hoṣea ọmọ Nuni;


Ẹni tí ó bá ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré yóo ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan ńlá.


Àwọn baba wa tí wọ́n tẹ̀lé Joṣua gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun lé kúrò níwájú wọn, lẹ́yìn náà wọ́n gbé àgọ́ náà wá. Àgọ́ yìí sì wà pẹlu wa títí di àkókò Dafidi.


Èmi Paulu, iranṣẹ Kristi Jesu, ni mò ń kọ ìwé yìí. Ọlọrun pè mí, ó fi mí ṣe òjíṣẹ́, ó sì yà mí sọ́tọ̀ láti máa waasu ìyìn rere rẹ̀.


Joṣua, ọmọ Nuni, tí ń ṣe iranṣẹ òun, ni yóo dé ilẹ̀ náà. Nítorí náà, ó ní kí n mú un lọ́kàn le, nítorí òun ni yóo jẹ́ kí Israẹli gba ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì jogún rẹ̀.


OLUWA fi iṣẹ́ lé Joṣua ọmọ Nuni lọ́wọ́, ó ní, “Múra gírí kí o sì mú ọkàn gidigidi, nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn ọmọ Israẹli wọ ilẹ̀ tí mo ti búra láti fún wọn. N óo wà pẹlu rẹ.”


OLUWA Ọlọrun yín tìkalára rẹ̀ ni yóo ṣiwaju yín lọ, yóo ba yín pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà run, tí ẹ ó fi lè gba ilẹ̀ wọn. Joṣua ni yóo sì jẹ́ olórí, tí yóo máa ṣiwaju yín lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí.


Ìre tí Mose eniyan Ọlọrun sú fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú nìyí. Ó ní:


Bẹ́ẹ̀ ni kò sí wolii mìíràn tí ó ní agbára ńlá tabi tí ó ṣe àwọn ohun tí ó bani lẹ́rù bí Mose ti ṣe lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.


Mose iranṣẹ OLUWA kú ní ilẹ̀ Moabu gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA.


Joṣua ọmọ Nuni kún fún ọgbọ́n nítorí pé Mose ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, nítorí náà àwọn ọmọ Israẹli ń gbọ́ tirẹ̀, wọ́n sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose.


Èmi Paulu, ẹrú Ọlọrun, ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí. Oluwa yàn mí láti jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ Ọlọrun lè ní igbagbọ ati ìmọ̀ òtítọ́ ti ẹ̀sìn,


Èmi Jakọbu, iranṣẹ Ọlọrun, ati ti Oluwa wa, Jesu Kristi, ni ó ń kọ ìwé yìí sí àwọn ẹ̀yà mejila tí ó fọ́nká gbogbo ayé. Alaafia fun yín!


títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti fun yín, tí wọn yóo sì fi gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fún wọn. Nígbà náà ni ẹ óo tó pada sí orí ilẹ̀ yín, tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fun yín ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, ẹ óo sì máa gbé ibẹ̀.”


“Mose iranṣẹ mi ti kú, nítorí náà, ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ẹ múra kí ẹ la odò Jọdani kọjá, kí ẹ sì wọ ilẹ̀ tí n óo fun yín.


Mose, iranṣẹ OLUWA ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba mejeeji yìí, ó sì pín ilẹ̀ wọn fún ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ilẹ̀ náà sì di tiwọn.


Èmi ni ẹni tí ó wà láàyè. Mo kú, ṣugbọn mo ti jí, mo sì wà láàyè lae ati laelae. Àwọn kọ́kọ́rọ́ ikú ati ti ipò òkú wà lọ́wọ́ mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan