Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 9:7 - Yoruba Bible

7 Ó wí fún un pé, “Lọ bọ́jú ninu adágún tí ó ń jẹ́ Siloamu.” (Ìtumọ̀ Siloamu ni “rán níṣẹ́.”) Ọkunrin náà lọ, ó bọ́jú, ó bá ríran.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 O si wi fun u pe, Lọ, wẹ̀ ninu adagun Siloamu, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ránlọ.) Nitorina o gbà ọ̀na rẹ̀ lọ, o wẹ̀, o si de, o nriran.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ó sì wí fún un pé, “Lọ wẹ̀ nínú adágún Siloamu!” (Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni “rán”). Nítorí náà ó gba ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó wẹ̀, ó sì dé, ó ń ríran.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 9:7
21 Iomraidhean Croise  

Ṣalumu ọmọ Kolihose, aláṣẹ agbègbè Misipa tún Ẹnubodè Orísun ṣe, ó tún un kọ́, ó bò ó, ó sì ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ ati ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, ó sì tún mọ odi Adágún Ṣela ti ọgbà ọba títí kan àtẹ̀gùn tí ó wá láti ìlú Dafidi.


A máa la ojú àwọn afọ́jú, a máa gbé àwọn tí a tẹrí wọn ba dúró; ó fẹ́ràn àwọn olódodo.


OLUWA dá a lóhùn pé, “Ta ló dá ẹnu eniyan? Ta ni í mú kí eniyan ya odi, tabi kí ó ya adití, tabi kí ó ríran, tabi kí ó ya afọ́jú? Ṣebí èmi OLUWA ni.


Àwọn tí wọ́n bá rí i kò ní dijú sí i, etí àwọn tí ó gbọ́ ọ kò ní di.


Ojú afọ́jú yóo là nígbà náà, etí adití yóo sì ṣí;


kí o lè la ojú àwọn afọ́jú, kí o lè yọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kúrò ni àhámọ́, kí o lè yọ àwọn tí ó jókòó ninu òkùnkùn kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.


Ẹ mú àwọn eniyan mi jáde, àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí ojú wọn ti fọ́, wọ́n ní etí, ṣugbọn etí wọn ti di.


“Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi kọ omi Ṣiloa tí ń ṣàn wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ sílẹ̀, wọ́n wá ń gbọ̀n jìnnìjìnnì níwájú Resini ati ọmọ Remalaya,


àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.


Tabi àwọn mejidinlogun tí ilé-ìṣọ́ gíga ní Siloamu wólù, tí ó pa wọ́n, ṣé ẹ rò pé wọ́n burú ju gbogbo àwọn eniyan yòókù tí ó ń gbé Jerusalẹmu lọ ni?


ìmọ́lẹ̀ láti fi ọ̀nà han àwọn kèfèrí ati ògo fún Israẹli, eniyan rẹ.”


kí ló dé tí ẹ fi sọ pé mò ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọrun ni mí,’ èmi tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó rán wá sí ayé?


Àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Ọkunrin yìí tí ó la ojú afọ́jú, ǹjẹ́ kò lè ṣe é kí ọkunrin yìí má fi kú?”


Ó dá wọn lóhùn pé, “Ọkunrin tí wọn ń pè ní Jesu ni ó po amọ̀, tí ó fi lẹ̀ mí lójú, tí ó sọ fún mi pé kí n lọ bọ́jú ní adágún Siloamu. Mo lọ, mo bọ́jú, mo sì ríran.”


Jesu bá ní, “Kí n lè ṣe ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran, kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.”


Kí á lè là wọ́n lójú, kí á sì lè yí wọn pada láti inú òkùnkùn sinu ìmọ́lẹ̀, kí á lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àṣẹ Satani, kí á sì fi wọ́n lé ọwọ́ Ọlọrun; kí wọ́n lè ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígbà mí gbọ́; kí wọ́n sì lè ní ogún pẹlu àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.’


Èyí jẹ́ nǹkan tí kò ṣe é ṣe lábẹ́ Òfin, nítorí eniyan kò lè ṣàì dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe é, nígbà tí ó dá ẹ̀bi ikú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu ẹ̀yà ara eniyan. Àní sẹ́, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí eniyan ẹlẹ́ṣẹ̀ láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́.


Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan